1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna

عن أبي هريرة رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«حُجِبَتِ النَّارُ بِالشَّهَوَاتِ، وَحُجِبَتِ الْجَنَّةُ بِالْمَكَارِهِ».

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ní dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Wọ́n fi awọn adùn tí eniyan n fẹ́ nifẹkufẹẹ rọkirika Iná ọ̀run, wọ́n sì fi awọn nkan tí ọkàn eniyan koriira rẹ̀ rọkirika Alujanna".

O ni alaafia Bukhaariy gba a wa Sọhiihu ti Bukhaariy - 6487

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé dajudaju awọn nkan tí ẹ̀mí eniyan n fẹ́ ni o wa ní ayika Iná ọ̀run, gẹgẹ bii ṣiṣe awọn nkan tí Ọlọhun ṣe ní eewọ tabi ikudiẹ-kaato nibi awọn ọranyan; Nitori naa ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ifẹẹnu rẹ̀ nibi ìyẹn, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Ina ọ̀run, àti pé dajudaju àwọn nkan tí ẹmi eniyan koriira rẹ̀ ni o wa ní ayika Alujanna; gẹgẹ bii ṣíṣe àwọn nkan tí Ọlọhun pa wá láṣẹ rẹ̀ déédé ati gbigbe àwọn nkan eewọ jù sílẹ̀ àti ṣíṣe sùúrù lori wọn, tí eniyan bá wá tiraka, tí ó sì gbiyanju pẹ̀lú ẹmi ara rẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, onitọhun ti lẹtọọ sí wiwọ Alujanna.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ninu awọn okunfa tí eniyan fi n kó sínú ifẹkufẹẹ adun aye ni kí èṣù kó ọ̀ṣọ́ bá awọn nkan naa, tí ó jẹ́ nkan buruku tí kò dara, títí eniyan o fi ri i pé ó dara, yoo sì ṣẹ́rí lọ si idi rẹ̀.
  2. Àṣẹ jíjìnà sí awọn adùn aye tó jẹ́ eewọ; nitori pe ọ̀nà ati wọ iná ni, ati ṣiṣe suuru lori awọn nkan tí ẹmi wa koriira rẹ̀; nitori pe ọ̀nà ati wọ Alujanna ni.
  3. Ọlá tí n bẹ fún jija ẹ̀mí ara ẹni lógun, ati gbígbìyànjú nibi ijọsin fun Ọlọhun, ati níní suuru lori awọn nnkan ti èèyàn koriira ati inira tí ó wà níbi titẹle ti Ọlọhun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

69 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو