1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”

عن ابن عباس رضي الله عنهما
عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فِيمَا يَرْوِي عَنْ رَبِّهِ عَزَّ وَجَلَّ قَالَ: قَالَ: «إِنَّ اللهَ كَتَبَ الْحَسَنَاتِ وَالسَّيِّئَاتِ، ثُمَّ بَيَّنَ ذَلِكَ، فَمَنْ هَمَّ بِحَسَنَةٍ فَلَمْ يَعْمَلْهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ حَسَنَةً كَامِلَةً، فَإِنْ هُوَ هَمَّ بِهَا فَعَمِلَهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ عَشْرَ حَسَنَاتٍ إِلَى سَبْعِمِائَةِ ضِعْفٍ، إِلَى أَضْعَافٍ كَثِيرَةٍ، وَمَنْ هَمَّ بِسَيِّئَةٍ فَلَمْ يَعْمَلْهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ عِنْدَهُ حَسَنَةً كَامِلَةً، فَإِنْ هُوَ هَمَّ بِهَا فَعَمِلَهَا كَتَبَهَا اللهُ لَهُ سَيِّئَةً وَاحِدَةً».

Lati ọdọ Ibnu Abbaas (ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji)
Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ti O lágbára ti O gbọnngbọn, o sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 6491

Àlàyé

Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun ti kádàrá dáadáa ati aburú, lẹyin naa O ṣàlàyé fun awọn malaika méjèèjì bi wọn ṣe maa kọ ọ:
Ẹni tí ó bá gbèrò ṣíṣe dáadáa, wọn maa kọ ọ fun un ni dáadáa ẹyọkan koda ki o ma ṣe e, ti o ba wa ṣe e, wọn maa ṣe adipele rẹ pẹlu ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ, alekun naa maa wa ni ibamu si bi ọkàn ba ṣe ni imọkanga sí, ati bi àwọn èèyàn ba ṣe ṣe anfaani latara rẹ̀ si, ati ohun ti o jọ ìyẹn.
Ẹni tí ó bá gbèrò lati ṣe aburu, lẹyin naa o wa gbe e ju silẹ, wọn maa kọ ọ fun ni dáadáa, ti ko ba wa raye ṣe e pẹlu pe ko ṣe àwọn okunfa rẹ, wọn ko nii kọ nǹkan kan, ti o ba gbe e ju silẹ ni ti ikagara, wọn maa kọ àníyàn rẹ fun un, ti o ba wa ṣe e, wọn maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe àlàyé ọla Ọlọhun ti o tobi lori ijọ yii nibi adipele àwọn dáadáa ati kikọ wọn ni ọdọ Rẹ, ati àìsí adipele fun aburu.
  2. Pataki aniyan ninu awọn iṣẹ ati oripa rẹ.
  3. Ọlá Ọlọhun ati aanu Rẹ ati dáadáa Rẹ ni pe ẹni ti o ba gbèrò dáadáa ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ ni dáadáa.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

69 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو