1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم أنه قال:
«وَالَّذِي نَفْسُ مُحَمَّدٍ بِيَدِهِ لَا يَسْمَعُ بِي أَحَدٌ مِنْ هَذِهِ الْأُمَّةِ يَهُودِيٌّ وَلَا نَصْرَانِيٌّ، ثُمَّ يَمُوتُ وَلَمْ يُؤْمِنْ بِالَّذِي أُرْسِلْتُ بِهِ إِلَّا كَانَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina".

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 153

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n bura pẹlu Ọlọhun pe ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa oun ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara tabi ẹni ti o yatọ si awọn mejeeji, ti ipepe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- de etiigbọ rẹ, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ ninu rẹ afi ki o wa ninu awọn ara ina ti o maa ṣe gbere nibẹ lailai.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikari ìránṣẹ́ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si gbogbo aye, ati pe itẹle rẹ jẹ dandan, ati pipa gbogbo àwọn ofin rẹ pẹlu Sharia rẹ.
  2. Ẹni ti o ba ṣe aigbagbọ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ini adisọkan igbagbọ rẹ pẹlu ẹni ti o yàtọ̀ si i ninu awọn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun maa ba wọn patapata- ko nii ṣe e ni anfaani.
  3. Ẹni ti ko ba gbọ nipa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti ipepe Isilaamu ko si de etiigbọ rẹ, oun jẹ ẹni ti o ni àwíjàre, alamọri rẹ ni ọrun si wa lọwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  4. Ṣíṣe anfaani pẹlu Isilaamu maa wa si ìmúṣẹ koda ki o jẹ pe o ku diẹ ti eeyan maa ku, koda ki o jẹ ninu aarẹ ti o le koko, niwọn igba ti ẹmi ko ba i tii de ọna ọfun.
  5. Titun ẹsin awọn alaigbagbọ ṣe- ti Juu ati Nasara n bẹ ninu wọn- jẹ aigbagbọ.
  6. Didarukọ Juu ati Nasara- ninu hadiisi náà- jẹ itaniji fun ẹni ti o yàtọ̀ si wọn; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe iwe n bẹ fun Juu ati Nasara, ti ọrọ wọn ba wa ri báyìí, a jẹ pe ẹni tí o yàtọ̀ si wọn ti iwe ko si fun wọn ni ẹtọ si i ju wọn lọ, ati pe gbogbo wọn, wiwọ inu ẹsin rẹ jẹ dandan fun wọn ati itẹle rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

59 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية