1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّهُ قَالَ:
قِيلَ: يَا رَسُولَ اللهِ، مَنْ أَسْعَدُ النَّاسِ بِشَفَاعَتِكَ يَوْمَ الْقِيَامَةِ؟ قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لَقَدْ ظَنَنْتُ يَا أَبَا هُرَيْرَةَ أَنْ لَا يَسْأَلَنِي عَنْ هَذَا الْحَدِيثِ أَحَدٌ أَوَّلُ مِنْكَ؛ لِمَا رَأَيْتُ مِنْ حِرْصِكَ عَلَى الْحَدِيثِ، أَسْعَدُ النَّاسِ بِشَفَاعَتِي يَوْمَ الْقِيَامَةِ، مَنْ قَالَ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ خَالِصًا مِنْ قَلْبِهِ أَوْ نَفْسِهِ»».

Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ó sọ pé:
Wọ́n sọ pé: Iwọ Ojiṣẹ Ọlọhun, ta ni yoo ṣoriire jù ninu awọn eniyan pẹlu ìṣìpẹ̀ rẹ ni ọjọ Igbende? Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - dahun bayii wi pe: "Irẹ Abu Hurairah, mo ti rò naa pé ko si ẹnikan ti yoo bi mi leere nipa hadiisi yii saaju rẹ, nigba ti mo ti ri itaraṣaṣa rẹ si imọ hadiisi, Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀".

O ni alaafia Bukhaariy gba a wa Sọhiihu ti Bukhaariy - 99

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fun wa ni iro pé dajudaju ẹniti ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ oun ni ọjọ Igbende ni ẹnikẹni tí ó bá sọ pé: "Ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah pẹlu ododo lati inu ọkan rẹ̀" iyẹn ni pe: ko si ẹnikẹni ti a gbọdọ jọsin fun pẹlu ododo ayafi Ọlọhun Allah, ati pe ó gbọdọ là kuro nibi ẹbọ ati kárími.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fífi ìṣìpẹ̀ rinlẹ̀ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ni ọjọ ikẹyin, ati pé ìṣìpẹ̀ naa ko nii sí fun ẹnikankan ayafi awọn tí wọ́n ṣe Ọlọhun lọ́kan ṣoṣo.
  2. Ìṣìpẹ̀ rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - oun ni ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ si Ọlọhun Ọba fun awọn tí ó yẹ kí wọ́n wọ ina Jahannama ninu awọn oluṣọlọhun lọ́kan pé kí wọ́n má wọ inu rẹ̀, ati pé kí awọn tí ó ti wà ninu ina lè jáde kuro ninu rẹ̀.
  3. Ọlá tí n bẹ fun gbolohun iṣọlọhun lọ́kan tó jẹ́ ododo mímọ́ fun Ọlọhun Ọba, ati títóbi orípa gbolohun naa.
  4. Gbolohun iṣọlọhun lọ́kan yoo maa di òtítọ́ pẹlu mímọ itumọ rẹ̀, ati fífi nǹkan ti o n bèèrè fun ṣiṣé ṣe.
  5. Ọlá tí n bẹ fún Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ati ìtaraṣàṣà rẹ̀ sí ìmọ̀.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

69 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو