1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo

عن جندب رضي الله عنه قال:
سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَبْلَ أَنْ يَمُوتَ بِخَمْسٍ وَهُوَ يَقُولُ «إِنِّي أَبْرَأُ إِلَى اللهِ أَنْ يَكُونَ لِي مِنْكُمْ خَلِيلٌ فَإِنَّ اللهَ تَعَالَى قَدِ اتَّخَذَنِي خَلِيلًا كَمَا اتَّخَذَ إِبْرَاهِيمَ خَلِيلًا، وَلَوْ كُنْتُ مُتَّخِذًا مِنْ أُمَّتِي خَلِيلًا لَاتَّخَذْتُ أَبَا بَكْرٍ خَلِيلًا! أَلَا وَإِنَّ مَنْ كَانَ قَبْلَكُمْ كَانُوا يَتَّخِذُونَ قُبُورَ أَنْبِيَائِهِمْ وَصَالِحِيهِمْ مَسَاجِدَ، أَلَا فَلَا تَتَّخِذُوا الْقُبُورَ مَسَاجِدَ! إِنِّي أَنْهَاكُمْ عَنْ ذَلِكَ».

Lati ọdọ Jundub, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe:
Mo gbọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, ní o ku ọdún márùn-ún tí ó fi maa jáde láyé, ti o ń sọ wípé: “Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo, ti emi ba ti ẹ fẹ mu ẹnikan ninu awọn ijọ mi ni ọrẹ aayo, emi i ba mu Abu Bakr ni ọrẹ aayo, ẹ gbọ o, dajudaju awọn ijọ tí wọ́n ti lọ síwájú yin a maa mú saare awọn Anabi ati awọn ẹniire inu wọn ni mọṣalaṣi, nitori naa, ẹ má ṣe mú awọn saare ni mọṣalaṣi, dajudaju emi n kọ ọ fún yín”.

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 532

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n fun wa ni iro nipa ipo rẹ̀ lọdọ Ọlọhun Ọba, ó n sọ pé ipo naa dé ipo ifẹ tó ga julọ, gẹgẹ bi Anabi Ibrahim – Alaafia fun un – ṣe de bẹ, nitori eyi ni Anabi fi sọ pe òun ò ni ọrẹ aayo kankan yatọ si Ọlọhun; nitori pé ọkàn oun ti kún kẹ́kẹ́ fún ìfẹ́ Ọlọhun Ọba ati gbigbe E tobi àti mímọ̀ ọ́n, nítorí náà kò sí ààyè ninu rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni yàtọ̀ sí Ọlọ́hun. Tí ó bá jẹ́ pé ó ní ọ̀rẹ́ aayo ninu àwọn ẹ̀dá ni, ìbá jẹ́ Abu Bakr As-Siddiq, kí Ọlọ́hun yọ́nú sí i. Lẹyin naa ó ní ka sọra kuro nibi ikọja aala ninu ifẹ, gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ti ṣe sí saare awọn anabi ati awọn ẹni rere inu wọn, titi ti wọn fi sọ wọn di ọlọrun ẹbọ ti wọn n jọsin fun wọn dipo Ọlọhun Allah, ti wọn sì kọ mọṣalaṣi ati ile ijọsin sori awọn saare wọn, Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ̀ fun awọn ijọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ ṣe gẹgẹ bi awọn Yahudi ati Nasara ṣe ṣe.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun Abu Bakr Siddiq - ki Ọlọhun yọnu si i- ati pé dajudaju oun ni ẹni tó lọ́lá jùlọ ninu awọn Sahaaba, oun ló sì lẹtọọ ju gbogbo eniyan lọ lati jẹ khalifa lẹyin iku Ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a).
  2. Dajudaju kikọ mọṣalaṣi sori awọn saare jẹ́ ọ̀kan ninu awọn aburu ti awọn ìjọ tó ṣaaju ṣe.
  3. kíkọ̀ fun wa lati mú awọn saare ni àáyè ijọsin ti ao waa maa kirun nibẹ tabi ki a maa kirun si oku ibẹ lara, ati kíkọ̀ fun wa lati kọ́ mọṣalaṣi tabi òrùlé rìbìtì sí ori awọn saare, kí ó lè jẹ́ iṣọra fun wa kuro nibi kíkó sinu ẹbọ latara iyẹn.
  4. Iwani ní iṣọra kuro nibi àṣejù nipa awọn ẹni rere, nitori pé ó máa ń fani lọ sí inu ẹbọ ni.
  5. Pípàtàkì ohun tí Anabi n wá wa ní isọra kuro ní idi rẹ̀ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nigba tí ó tẹnumọ ọn ní ó ku ọjọ márùn-ún ti yio jade laye.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

68 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو