1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لاَ عَدْوَى وَلاَ طِيَرَةَ، وَلاَ هَامَةَ وَلاَ صَفَرَ، وَفِرَّ مِنَ المَجْذُومِ كَمَا تَفِرُّ مِنَ الأَسَدِ».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 5707

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn àlámọ̀rí asiko aimọkan ni ti siṣekilọ kuro nibẹ, ati ṣíṣe àlàyé pe dajudaju àlámọ̀rí ọwọ Ọlọhun ni o wa, ati pe nnkan kan ko le ṣẹlẹ̀ afi pẹlu àṣẹ Rẹ ati kadara Rẹ, awọn ni:
Akọkọ: Awọn ara asiko aimọkan n lero pe dajudaju aisan maa n ran fun ara rẹ; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ kuro nibi adisọkan ṣíṣí aisan latara alaisan sọ́dọ̀ ẹlòmíràn fúnra rẹ; Ọlọhun ni n ṣàkóso ayé; Oun ni O n sọ aisan kalẹ ti O si n gbe e kuro, ìyẹn ko lee ṣẹlẹ̀ afi pẹlu fifẹ Rẹ ati kadara Rẹ.
Ikeji ni: Awọn ara asiko aimọkan ti wọn ba jade fun ìrìn-àjò tabi òwò, wọn maa lé ẹyẹ lọ, ti o ba fo si agbegbe ọtun wọn maa dunnu, ti o ba fo si agbegbe osi wọn maa fura mọ aburu wọn si maa ṣẹri pada, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu yii pẹlu ẹyẹ, ti o si ṣàlàyé pe adisọkan ibajẹ ni.
Ikẹta: Awọn ara asiko aimọkan maa n sọ pe: Ti ẹyẹ owiwi bá bà lori ile kan, àjálù kan maa ṣẹlẹ̀ si awọn ara ile náà; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu ìyẹn.
Ikẹrin: O kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu oṣu safar, oun ni oṣu keji ninu awọn oṣu ti òṣùpá. Wọ́n tún sọ pé 'Safar' jẹ́ ejò tó ń gbé inú ikùn, tó ń ṣàkóbá fún ẹran ọ̀sìn àti ènìyàn. Wọ́n sọ pé ó máa ń ranni ju àrùn ìgbóná lọ; ni o wa tako adisọkan yii.
Ikarun-un: Ó pàṣẹ pé kí wọ́n yẹra fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá n bẹ lára rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ṣe yẹra fún kìnnìún, gẹ́gẹ́ bí ìṣọ́ra fún ara rẹ, ati wiwa ààbò fun un, àti ṣíṣe àwọn ìdí tí Ọlọhun pa láṣẹ. Ẹ̀tẹ̀ jẹ́: Àìsàn tó máa ń ba àwọn ẹ̀yà ara jẹ́.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ijẹ-dandan igbarale Ọlọhun ati fifi ara ti I, ati ṣíṣe awọn okunfa ti a ṣe lofin.
  2. Jijẹ dandan ini igbagbọ ninu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, ati pe dajudaju awọn okunfa wa lọwọ Ọlọhun, Oun ni O maa n mu wọn ṣẹlẹ̀ ti O si maa n ka ilapa wọn kuro.
  3. Biba nnkan ti awọn kan ninu awọn eniyan maa n ṣe jẹ bii èrò òdì nípa àwọ̀, bíi àwọ̀ dúdú àti àwọ̀ pupa, tàbí nípa àwọn nọ́ńbà kan, orúkọ, àwọn èèyàn àtàwọn aláàbọ̀ ara.
  4. Nibi idinamọ isunmọ adẹtẹ ati iru rẹ ninu awọn ti wọn ni awọn aisan ti wọn maa n ran; ó wà lára àwọn ìdí tí Ọlọ́run maa n jẹ ki o sáábà maa n fa irú àrùn bẹ́ẹ̀; ati pe awọn okunfa ko lee da duro fun ara rẹ, bi ko ṣe pe Ọlọhun ni Ẹni ti o ṣe pe ti O ba fẹ O maa gba agbára lọ́wọ́ rẹ̀ ti ko si nii lapa kankan, ti O ba si fẹ O maa ṣẹ ẹ ku ki o lapa.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية