1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un

‌عن عَلِيٍّ قَالَ: إِنِّي كُنْتُ رَجُلًا إِذَا سَمِعْتُ مِنْ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ حَدِيثًا نَفَعَنِي اللهُ مِنْهُ بِمَا شَاءَ أَنْ يَنْفَعَنِي بِهِ، وَإِذَا حَدَّثَنِي رَجُلٌ مِنْ أَصْحَابِهِ اسْتَحْلَفْتُهُ، فَإِذَا حَلَفَ لِي صَدَّقْتُهُ، وَإِنَّهُ حَدَّثَنِي ‌أَبُو بَكْرٍ، وَصَدَقَ أَبُو بَكْرٍ، قَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«مَا مِنْ رَجُلٍ يُذْنِبُ ذَنْبًا، ثُمَّ يَقُومُ فَيَتَطَهَّرُ، ثُمَّ يُصَلِّي، ثُمَّ يَسْتَغْفِرُ اللهَ، إِلَّا غَفَرَ اللهُ لَهُ»، ثُمَّ قَرَأَ هَذِهِ الْآيَةَ: {وَالَّذِينَ إِذَا فَعَلُوا فَاحِشَةً أَوْ ظَلَمُوا أَنْفُسَهُمْ ذَكَرُوا اللهَ فَاسْتَغْفَرُوا لِذُنُوبِهِمْ} [آل عمران: 135].

Lati ọdọ ‘Aliyy o sọ pe: Dajudaju mo jẹ ọkunrin kan ti o ṣe pe ti mo ba ti gbọ ọrọ kan lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - Ọlọhun maa n fi nkan ti O ba fẹ ṣe mi ni anfaani pẹlu rẹ, ti ẹnikẹni ba wa sọrọ fun mi ninu awọn saabe rẹ (Anabi) maa ni ki o bura, ti o ba ti wa bura fun mi maa gba a gbọ, Abubakar wa sọrọ fun mi, ododo si ni Abubakar sọ, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
«Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un», lẹyin naa ni o wa ka aaya yii: {Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn} [Āl ‘Imraan: 135].

O ni alaafia Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah ati Ahmad Sunanu ti Tirmidhiy - 406

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ko si ẹru kan ti yio da ẹṣẹ kan, ti yio wa se aluwala daadaa, lẹyin naa ti yio ki irun rakaah meji pẹlu aniyan ituuba kuro nibi ẹṣẹ rẹ yii, lẹyin naa ti o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun fi ori jin in. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ka ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe: ﴾Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni).﴿ [Āl ‘Imraan: 135].

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe lojukokoro lori irun lẹyin naa wiwa aforijin lẹyin ẹṣẹ.
  2. Gbigbaaye aforijin Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ati gbigba tituba ati iwaforijin Rẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية