1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi “Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”

عن أبي سعيد الخدري رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«لَا ضَرَرَ وَلَا ضِرَارَ، مَنْ ضَارَّ ضَرَّهُ اللَّهُ، وَمَنْ شَاقَّ شَقَّ اللَّهُ عَلَيْهِ».

Láti ọ̀dọ̀ Abu Saheed Al-Khudriy- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ma ṣe maa ni eeyan lara, ma ṣe maa gba ẹsan ìnira, ẹni tí ó bá fi ara ni èèyàn, Ọlọhun yoo fi ara ni in, ẹni tí ó bá ko ìpalára ba èèyàn, Ọlọhun yoo ko ìpalára ba a”.

O ni alaafia pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí rẹ Daarukutniy ni o gba a wa Sunanu ti Daarukutniy - 3079

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dandan ni ki eeyan ti aburu dànù kuro lọ́dọ̀ ara ẹni ati kúrò lọ́dọ̀ ẹlòmíràn, iru inira yòówù ko ri ki o jẹ, ko ni ẹtọ fun ẹnikẹ́ni ki o fi suta kan ara rẹ tabi ẹlòmíràn láìsí iyatọ.
Ko si ni ẹtọ fun un ki o fi oró yaró; tori pe a kìí mu inira kúrò pẹ̀lú ìnira ayafi ti a ba fẹ gba ẹsan láìní kọjá ààlà.
Lẹyin naa ni Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣàlàyé àdéhùn ìyà ìpalára fun ẹni tí ba n ko ìpalára ba àwọn èèyàn, ati ìnira fun ẹni tí ba n ko ìnira ba àwọn èèyàn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Idinamọ gbigba ẹsan pẹlu nǹkan ti o ju iru aburu ti wọn fi kan èèyàn lọ.
  2. Ọlọhun ko pa ẹrú Rẹ ni àṣẹ pẹlu nǹkan ti o maa ko ìnira ba wọn.
  3. Ṣíṣe ifi inira kan èèyàn ati gbigba ẹsan inira pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tabi ìṣe tabi gbigbe ju silẹ ni eewọ.
  4. Ẹsan maa wa latara ìran iṣẹ, ẹni ti o ba ko ìpalára ba ẹlòmíì, Ọlọhun maa ko ìpalára ba a, ẹni tí ó bá fi ara ni ẹlòmíì, Ọlọhun maa fi ara ni oun naa.
  5. Ọkan ninu awọn ofin Sharia ni pe: “A maa n mu ipalara kuro ni.” Sharia ko fi ọwọ́ si ipalara, o si kọ ipalara.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

68 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو