1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun

عن ابن عباس رضي الله عنهما قال:
كُنْتُ خَلْفَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَوْمًا، فَقَالَ: «يَا غُلَامُ، إِنِّي أُعَلِّمُكَ كَلِمَاتٍ، احْفَظِ اللهَ يَحْفَظْكَ، احْفَظِ اللهَ تَجِدْهُ تُجَاهَكَ، إِذَا سَأَلْتَ فَاسْأَلِ اللهَ، وَإِذَا اسْتَعَنْتَ فَاسْتَعِنْ بِاللهِ، وَاعْلَمْ أَنَّ الْأُمَّةَ لَوِ اجْتَمَعَتْ عَلَى أَنْ يَنْفَعُوكَ بِشَيْءٍ، لَمْ يَنْفَعُوكَ إِلَّا بِشَيْءٍ قَدْ كَتَبَهُ اللهُ لَكَ، وَلَوِ اجْتَمَعُوا عَلَى أَنْ يَضُرُّوكَ بِشَيْءٍ، لَمْ يَضُرُّوكَ إِلَّا بِشَيْءٍ قَدْ كَتَبَهُ اللهُ عَلَيْكَ، رُفِعَتِ الْأَقْلَامُ وَجَفَّتِ الصُّحُفُ».

Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe:
“Mo wa lẹyin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni ọjọ kan, o wa sọ pe: “Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun. Mọ pe ti gbogbo ẹda ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe anfaani fun ọ, wọn ko nii ṣe àǹfààní kankan fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Ọlọhun ti kọ fun ọ. Ati pe ti wọn ba pejọ lati ṣe nkan lati ṣe ipalara fun ọ, wọn ko nii ṣe ipalara fun ọ rara ayafi pẹ̀lú nǹkan ti Allah ti kọ fun ọ. Wọn ti gbé àwọn ìkọ̀wé sókè, àwọn tákàdá si ti gbẹ.”

O ni alaafia Tirmiziy ni o gba a wa Sunanu ti Tirmidhiy - 2516

Àlàyé

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pé oun kéré nígbà tí oun n gun nǹkan ọ̀gùn pẹ̀lú Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa sọ pé: Mo maa kọ ẹ ni àwọn nǹkan kan ti Ọlọhun maa jẹ ki wọn ṣe ọ ni anfaani:
Ṣọ́ Ọlọhun pẹlu ṣiṣọ àwọn àṣẹ Rẹ̀ ati jíjìnnà si awọn nǹkan tí O kọ̀, ki O maa ri ọ nibi itẹle àṣẹ Rẹ ati awọn iṣẹ ti a fi n sunmọ Ọlọhun, ki O si má ri ọ nibi awọn ìyapa ati ẹṣẹ, tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀san rẹ ni kí Ọlọ́run dáàbò bò ọ lọ́wọ́ nǹkan ìkórìíra ayé àti ọjọ́ ìkẹyìn, yoo sì ràn ọ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ rẹ níbikíbi tí o bá lọ.
Ti o ba fẹ tọrọ nnkan, Ọlọhun nikan ni ki o bi; tori pe Oun nikan ni O maa n da onibeere lóhùn.
Ti o ba fẹ iranlọwọ, Ọlọhun nìkan ni ki o wa iranlọwọ Rẹ̀.
Ki o ni amọdaju pe anfaani kankan ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ará ilẹ̀ kójọ lati ṣe ọ ni anfaani ayafi ohun ti Ọlọhun ba kọ fun ẹ, inira kankan ko si lee ṣẹlẹ̀ si ẹ kódà ki gbogbo àwọn ara ilẹ̀ kójọ láti fi ìnira kan ọ àyàfi ohun tí Ọlọhun ba ti kádàrá fun ẹ.
Ati pe Ọlọhun ti kọ àlámọ̀rí yii, O si kádàrá rẹ ni ibamu si ọgbọ́n àti imọ Rẹ, ko si àyípadà fun nǹkan ti Ọlọhun kọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pataki kikọ àwọn ọmọ kéékèèké ni ọrọ ẹsin bii imọ imu-Ọlọhun-lọkan àti àwọn ẹkọ ati nǹkan ti o yatọ si ìyẹn.
  2. Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ.
  3. Pipaṣẹ igbarale Ọlọhun, ati igbẹkẹle E yatọ si ẹlomiran, Ó sì dára ni Alámòójútó.
  4. Igbagbọ nínú kádàrá ati yiyọnu si i, ati pe Ọlọhun ni O kádàrá gbogbo nǹkan.
  5. Ẹni ti o ba ra àṣẹ Ọlọhun lare, Ọlọhun maa ra oun naa lare, ko si nii ṣọ́ ọ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

69 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو