1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin

عن ابن عمر رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«كل مُسْكِرٍ خَمْرٌ، وكل مُسْكِرٍ حرام، ومن شرِب الخمر في الدنيا فمات وهو يُدْمِنُهَا لَمْ يَتُبْ، لَمْ يَشْرَبْهَا في الآخرة».

Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin».

O ni alaafia رواه مسلم وأخرج البخاري الجملة الأخيرة منه Sọhiihu ti Muslim - 2003

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe alaye pe dajudaju gbogbo nkan ti o ba ti le mu laakaye lọ ni ọti ti n pa eeyan, yala o jẹ mímu tabi jijẹ tabi fifin simu tabi eyi ti o yato si i, ati pe dajudaju gbogbo nkan ti o le muni maa hunrira ti O si maa pa laakaye ni Ọlọhun Ọba ti O biyi ti O gbọnngbọn ti ṣe e ni eewọ ti O si tun kọ kuro nibẹ, kekere rẹ ni ati pipọ rẹ, Ati pe gbogbo ẹni ti o ba mu èyíkéyìí ninu awọn iran nkan ti o máa ń muni hunrira, ti o tun wa dunni mọ mimu un ti ko si tun tuuba ninu rẹ ti o fi ku; onítọ̀hún ti lẹtọọ si Iya Ọlọhun pẹlu ṣiṣe mimu un ni eewọ fun un ninu al-jannah.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Okunfa ṣiṣe ọtí ni eewọ ni pipani, nitori naa gbogbo nkan ti o ba ti n pani, iran yòówù ki o jẹ, èèwọ̀ ni.
  2. Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ọtí ni eewọ latari nkan ti o ko sinu ni awọn inira ati awọn ibajẹ ti o tobi.
  3. Mimu ọtí ninu al-jannah ninu pipe adun ati idẹkun ni o wa.
  4. Ẹni ti ko ba ko ẹmi rẹ ro nibi ọti mimu ni ayé, Ọlọhun yoo ṣe mimu rẹ ni eewọ fun un ninu al-jannah, nítorí pé igba ti wọn ba fi wínkà ni wọn fi n san an.
  5. Ṣiṣenilojukokoro lori yiyara tuuba kuro nibi ẹṣẹ ṣaaju iku.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

61 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو