1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi “Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”

عن طارق بن أشيم الأشجعي رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ قَالَ: لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَكَفَرَ بِمَا يُعْبَدُ مِنْ دُونِ اللهِ حَرُمَ مَالُهُ وَدَمُهُ، وَحِسَابُهُ عَلَى اللهِ».

Lati ọdọ Tooriq ọmọ Ashyam Al-Ash-ja'iy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”.

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 23

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba sọ ti o si jẹrii pẹlu ahọn rẹ pe “LAA ILAAHA ILLALLOHU”, o n túmọ̀ si pe: Ko si ẹni ti a le jọsin fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ afi Ọlọhun, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn jọsin fun yatọ si Ọlọhun, ti o bọpa-bọsẹ kuro nibi gbogbo awọn ẹsin yatọ si Isilaamu, dajudaju dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ jẹ eewọ fun awọn Musulumi, ohun ti ó kàn wa ni eyi ti o han ninu iṣẹ rẹ, wọn ko nii gba dukia rẹ, wọn ko si nii ta ẹjẹ rẹ silẹ, afi ti o ba da ẹṣẹ kan tabi wuwa ọdanran kan ti o maa sọ ìyẹn di dandan ni ìbámu si awọn idajọ Isilaamu.
Ati pe Ọlọhun ni yoo ṣe ìṣirò rẹ ni ọjọ igbedide, ti o ba jẹ olododo yoo san an lẹsan, ti o ba jẹ sọbẹ-selu yoo fi iya jẹ ẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Sisọ LAA ILAAHA ILLALLOHU, ati ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, jẹ majẹmu nibi wiwọ inu Isilaamu.
  2. Itumọ (LAA ILAAHA ILLALLOHU) ni ṣíṣe aigbagbọ pẹlu gbogbo nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun ninu awọn oosa ati awọn sàréè ati nnkan ti o yatọ si wọn, ati mimu U- mimọ ni fun Un- ni Ọkan ṣoṣo pẹlu ijọsin.
  3. Ẹni ti o ba mu ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan wa ti o si dunni mọ awọn ofin rẹ ni ti gbangba, ikoraro kuro fun un jẹ dandan titi ti nnkan ti o yatọ si ìyẹn yoo fi han lati ọdọ rẹ.
  4. Jijẹ eewọ dukia Musulumi ati ẹjẹ rẹ ati iyì rẹ afi pẹlu ẹtọ.
  5. Idajọ ni aye wa lori nǹkan ti o ba hàn, o si wa lori awọn aniyan ati awọn erongba ni ọrun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

63 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية