1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ

عَنْ سُلَيْمَانَ بْنِ صُرَدٍ رضي الله عنه قَالَ:
كُنْتُ جَالِسًا مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ وَرَجُلاَنِ يَسْتَبَّانِ، فَأَحَدُهُمَا احْمَرَّ وَجْهُهُ، وَانْتَفَخَتْ أَوْدَاجُهُ، فَقَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «إِنِّي لَأَعْلَمُ كَلِمَةً لَوْ قَالَهَا ذَهَبَ عَنْهُ مَا يَجِدُ، لَوْ قَالَ: أَعُوذُ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ، ذَهَبَ عَنْهُ مَا يَجِدُ» فَقَالُوا لَهُ: إِنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ: «تَعَوَّذْ بِاللَّهِ مِنَ الشَّيْطَانِ»، فَقَالَ: وَهَلْ بِي جُنُونٌ؟

Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe:
Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) sọ pé: "Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ ni wọ́n bá sọ fún un pe: dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "yáa wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù" (Satani), Arakunrin náà bá dahun pe: Se weere kọlu mi ni bi?

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 3282

Àlàyé

Arakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde.
Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe.
Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani).
Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nifẹ ki o máa ṣe itọsọna ati itunise nigbati o ba ti rí okunfa rẹ.
  2. Lati ọdọ èṣù (Satani) ni ibinu ti nwá.
  3. Ipani lasẹ lati wa isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe nigbati a ba nbinu, Ọlọhun Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ bayi pe: (Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ èṣù (Satani), fi Allāhu wá ìṣọ́rí ...) dé ìparí aayah.
  4. Isọni lára nibi imaa bu yàn ati nkan mi to tun jọ ọ gẹgẹbí epe ṣiṣẹ, ati ileni kúrò níbi awọn mejeeji, nitori pe a maa mu ibajẹ ṣẹlẹ làárin awọn ènìyàn.
  5. Mímú ọrọ ìmọràn, (ìkìlọ) lọ ba ẹni tí kò tii gbọ ọ; ki o le se anfaani pẹlu nkan to wa nibẹ, ki o si le wúlò fun un.
  6. Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti sọ wa lara nibi ibinu; nitoripe aa maa tini lọ síbi aburú ati isiwawu, Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a) kii dede binu ayaafi ti wọ́n bá fa ọgbà Ọlọhun ya nìkan, oun náà ni ìbínú ti ó da.
  7. An-Nawawi sọ ọrọ asọle lórí ọrọ rẹ "njẹ moya were ni bi": o le tumọ sí pé ẹni tí o sọrọ jẹ ọkan ninu awọn a seyi sọun (munaafiki), tàbí kí o jẹ ọkan ninu awọn lárúbáwá oko toluko.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

50 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية