1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi “Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”

عن عبد الله بن مسعود رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«إنَّ الرُّقَى والتَمائِمَ والتِّوَلَةَ شِرْكٌ».

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'hud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Dájúdájú ọfọ̀ ati àsokọ́ra ati oògùn ifẹran, ẹbọ ni”

O ni alaafia Abu Daud ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa Sunanu ti Abu Daud - 3883

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé àwọn nǹkan ti ṣíṣe wọn wa ninu ẹbọ, ninu wọn ni:
Akọkọ: Ọfọ̀: Oun ni ọ̀rọ̀ ti àwọn ara àsìkò ki Isilaamu to de fi maa n ṣe ìwòsàn, ti o ni ẹbọ nínú.
Ìkejì: Àsokọ́ra lati ara ìlẹ̀kẹ̀ ati nǹkan ti o jọ ọ: Eyi ti wọn maa n so kọ ọmọdé lọrun, ati awọn ẹran-ọ̀sìn, ati nǹkan ti o yatọ si i, lati ti ojukoju dànù.
Ikẹta: Oogun ifẹran: Eyi ti wọn ṣe lati jẹ ki ọkọ ati ìyàwó nífẹ̀ẹ́ ara wọn.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí wa nínú ẹbọ; torí pé o wa ninu fifi nǹkan ṣe okùnfà, ti kii sii ṣe okùnfà ti o ba òfin mu ti o rinlẹ pẹ̀lú ẹ̀rí, kii sii ṣe okùnfà ti ìmọ̀lára ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí. Ṣùgbọ́n àwọn òkùnfà ti o ba ofin mu gẹ́gẹ́ bii kika Kuraani, tabi eyi ti o jẹ ti ìmọ̀lára gẹ́gẹ́ bii àwọn oògùn ti o rinlẹ pẹ̀lú ìrírí, èyí ni ẹtọ pẹlu adisọkan pe okùnfà ni, ati pe àǹfààní ati ìnira wa lọ́wọ́ Ọlọhun.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣọ taohid ati adisọkan kúrò nibi nǹkan ti o maa ba a jẹ́.
  2. Ṣíṣe lilo ọfọ ti ẹlẹbọ ati àsokọ́ra ati oogun ifẹran ni eewọ.
  3. Adisọkan ọmọniyan nipa awọn mẹtẹẹta yii pe okùnfà ni wọn: Oun ni ẹbọ kekere; torí pé o ṣe ohun ti kii ṣe okùnfà ni okùnfà, ṣùgbọ́n ti o ba ni adisọkan pe oun ni yoo ṣe anfaani tabi fa inira funra rẹ, ìyẹn ni ẹbọ ńlá.
  4. Ikilọ kuro nibi ṣíṣe àwọn òkùnfà ti ẹlẹbọ ati eyi ti o jẹ eewọ.
  5. Ṣíṣe ọfọ ni eewọ, ati pe ẹbọ ni, ayafi eyi ti o ba ba sharia mu.
  6. O tọ́ ki ọkàn rọ̀ mọ́ Ọlọhun nìkan, ọdọ Rẹ ni ìnira ati àǹfààní ti n wa, ko ni orogun, ko si ẹni ti o le mu oore wa ayafi Ọlọhun, ko si si ẹni ti o le ti aburu lọ ayafi Ọlọhun.
  7. Ọfọ ti o tọ́ ni eyi ti o ko májẹ̀mú mẹta sinu: 1- Ki a ni adisọkan pe okùnfà ni wọn, wọn ko lee ṣe anfaani ayafi pẹ̀lú iyọnda Ọlọhun. 2- Ki wọn jẹ pẹlu Kuraani ati awọn orukọ Ọlọhun ati awọn iroyin Rẹ, ati awọn adua ti Anọbi, ati awọn adua ti wọn ba sharia mu. 3- Ki wọn jẹ pẹlu èdè ti a gbọye, ti ko si nii ni ìwé oògùn ati ẹtan ninu.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

68 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
RN Kirundi الكيروندي
YAO Yao الياو
KMR Kurmancî الكرمنجية