عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«إِيَّاكُمْ وَالظَّنَّ؛ فَإِنَّ الظَّنَّ أَكْذَبُ الْحَدِيثِ، وَلَا تَحَسَّسُوا، وَلَا تَجَسَّسُوا، وَلَا تَحَاسَدُوا، وَلَا تَدَابَرُوا، وَلَا تَبَاغَضُوا، وَكُونُوا عِبَادَ اللهِ إِخْوَانًا».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ, ẹ ma ṣe maa ọ̀nà láti tu ihoho ara yin sita, ki ẹ si ma maa tọpinpin ara yin, ki ẹ si ma maa ṣe keeta ara yín, ki ẹ si ma maa kọ ẹyin si ara yin, ki ẹ si ma maa korira ara yín, ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 6064

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ o si n kilọ kuro nibi awọn kan ninu nnkan ti o le bi opinya ati ọta laaarin awọn Musulumi, Ninu ìyẹn ni:
(Az zonnu) oun ni ikẹfin ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ọkan laini ẹri; o si ṣàlàyé pe o wa ninu eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ.
Ati kuro nibi (At tahassus): Oun ni wiwadii nipa awọn ihoho awọn eniyan pẹlu oju tabi etí.
Ati (At-tajassus): Oun ni wiwadii nipa nnkan ti o pamọ ninu awọn alamọri, ibi tí wọ́n ti maa n sọ ìyẹn ju ni nibi aburú.
Ati kuro nibi: (Al hasad) oun ni ikorira ṣiṣẹlẹ idẹra fun awọn ẹlomiran.
Ati kuro nibi (At tadaabur) ki awọn kan ninu wọn maa gbúnrí kúrò lọ́dọ̀ awọn kan, ko nii salamọ, ko si nii ṣe abẹwo ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí,
Ati kuro nibi: (At tabaagud) ati ikorira ati jíjìnnà-sini, gẹgẹ bii fifi suta kan awọn ẹlomiran, ati lile oju ati aima pade ara ẹni dáadáa.
Lẹyin naa, o sọ gbolohun ṣókí kan ti o ko nǹkan ti o pọ sínú ti o maa tun awọn isẹsi awọn Musulumi ṣe pẹlu ara wọn: (ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya) Ati pe ìjẹ́ ọmọ iya jẹ asopọ kan ti awọn ajọṣepọ laaarin awọn eniyan fi maa n lẹ̀ pọ̀, ti o maa n lekun ifẹ ati irẹpọ láàárín wọn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Aba dida burúkú ko ki n ko inira ba ẹni ti awọn ami rẹ ba han lara rẹ, o wa jẹ dandan fun olugbagbọ lati jẹ ẹni ti o gbọn ninu ati lẹyin ti ko nii gba ẹtanjẹ pẹlu awọn ẹni buruku ati awọn pooki.
  2. Nǹkan ti a gba lero ni ikilọ kúrò nibi kikẹfin ti o maa n rinlẹ ninu ẹmi, ati titaku lori rẹ, sugbọn eyi ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ẹmi ti ko rinlẹ, eleyii wọn ko la a bọ ọ lọrun.
  3. Ṣíṣe awọn okunfa ìkórìíra-ara-ẹni ati opinya laaarin ẹni kọọkan ninu àwùjọ Musulumi leewọ, bii itọpinpin ati keeta ati nnkan ti o jọ mejeeji.
  4. Asọtẹlẹ pẹlu biba Musulumi lo ni ibalo ọmọ iya nibi igbani ni ìmọ̀ràn ati ini ifẹ ara ẹni.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

59 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية