1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”

عَنْ ‌مَحْمُودِ بْنِ لَبِيدٍ رضي الله عنه:
أَنَّ ‌عُثْمَانَ بْنَ عَفَّانَ أَرَادَ بِنَاءَ الْمَسْجِدِ فَكَرِهَ النَّاسُ ذَلِكَ، وَأَحَبُّوا أَنْ يَدَعَهُ عَلَى هَيْئَتِهِ، فَقَالَ: سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ: «مَنْ بَنَى مَسْجِدًا لِلهِ بَنَى اللهُ لَهُ فِي الْجَنَّةِ مِثْلَهُ».

Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labid- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i kalẹ bi o ṣe wa, o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Muslim - 533

Àlàyé

Uthman ọmọ ‘Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- fẹ tun mọsalasi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ni irisi ti o daa ju kikọ akọkọ rẹ lọ, ni awọn eniyan ba korira ìyẹn; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu yiyi kikọ mọsalasi naa pada kuro nibi isẹsi kikọ rẹ ni aye Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mọsalasi jẹ nnkan ti wọn mọ pẹlu amọ̀, ati pe òrùlé rẹ wọn mọ ọn latara imọ̀ ọ̀pẹ, ṣugbọn Uthman fẹ kọ ọ pẹlu awọn okuta ati ẹfun, Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun wọn nipa rẹ, ati pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lati fi wa iyọnu Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- ti ko kii ṣe ni ti karimi tabi kagbọmi, Ọlọhun A san-an lẹsan ni eyi ti o daa julọ ninu ẹsan ninu iran iṣẹ rẹ, ati pe ẹsan yii oun ni ki Ọlọhun kọ iru rẹ fun un ninu alujanna.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣisẹnilojukokoro lori kikọ awọn mọsalasi ati ọla ti o n bẹ fun ìyẹn.
  2. Fifẹ mọsalasi ati titun un ṣe wọnu ọla ti o n bẹ fun kikọ ọ.
  3. Pataki imọkanga fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi gbogbo iṣẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

61 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية