1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ

عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المؤمنين رضي الله عنها:
أَنَّ أُمَّ سَلَمَةَ ذَكَرَتْ لِرَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَنِيسَةً رَأَتْهَا بِأَرْضِ الْحَبَشَةِ، يُقَالُ لَهَا مَارِيَةُ، فَذَكَرَتْ لَهُ مَا رَأَتْ فِيهَا مِنَ الصُّوَرِ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «أُولَئِكَ قَوْمٌ إِذَا مَاتَ فِيهِمُ الْعَبْدُ الصَّالِحُ، أَوِ الرَّجُلُ الصَّالِحُ، بَنَوْا عَلَى قَبْرِهِ مَسْجِدًا، وَصَوَّرُوا فِيهِ تِلْكَ الصُّوَرَ، أُولَئِكَ شِرَارُ الْخَلْقِ عِنْدَ اللهِ».

Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju Ummu Salamah dárúkọ ṣọọṣi kan ti o ri ni ilẹ̀ Habasha fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, wọn n pe e ni Maariyah, o wa sọ nnkan ti o ri nibẹ fun un ninu awọn aworan, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ, wọn yoo si ya awọn aworan yẹn síbẹ̀, awọn wọnyẹn ni awọn ti wọn buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 434

Àlàyé

Iya awọn olugbagbọ Ummu Salamah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe dajudaju nigba ti oun fi wa lori ilẹ Habasha, oun ri ṣọọṣi kan- wọn n pe e ni Maariyah- ti awọn aworan ati awọn ẹṣọ ati awọn fọto n bẹ nibẹ; ni ti ìyàlẹ́nu latara ìyẹn! Bayii ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba ṣàlàyé awọn okunfa gbigbe awọn aworan yii síbẹ̀; O sọ pe: Dajudaju awọn ti o dárúkọ wọnyii ti ẹni rere ba ku laaarin wọn, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ ti wọn ma maa kirun nibẹ, ti wọn si maa ya awọn aworan yẹn, O ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe yẹn jẹ ẹni ti o buru julọ ninu ẹda lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-; nitori pe iṣe rẹ maa ja si dida orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe kikọ awọn mọsalasi lori awọn saare leewọ, tabi kiki irun nibẹ, tabi sisin awọn oku si awọn mọsalasi; lati dina mọ okunfa ẹbọ ṣíṣe.
  2. Kikọ awọn mọsalasi lori awọn saare, ati gbigbe awọn aworan síbẹ̀, jẹ iṣẹ Juu ati Nasara, ati pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe èyí, dajudaju o ti fi iwa jọ wọn.
  3. Ṣíṣe yiya aworan awọn nnkan ti wọn ni ẹmi leewọ.
  4. Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lori saare ti o si ya awọn aworan síbẹ̀, o ti wa ninu ẹni ti o buru julọ ninu ẹda Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  5. Idaabo bo Sharia fun agbegbe imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo jẹ idaabo bo kan ti o pe, pẹlu kikọdi gbogbo ọna ti o le ja si ẹbọ ṣiṣe.
  6. Kikọ kuro nibi aṣẹju nipa awọn ẹni rere; nitori pe o jẹ okunfa kiko sinu ẹbọ ṣíṣe.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

60 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية