1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ

عن أَبي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه:
أنه كَانَ يُكَبِّرُ فِي كُلِّ صَلَاةٍ مِنَ الْمَكْتُوبَةِ وَغَيْرِهَا، فِي رَمَضَانَ وَغَيْرِهِ، فَيُكَبِّرُ حِينَ يَقُومُ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْكَعُ، ثُمَّ يَقُولُ: سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، ثُمَّ يَقُولُ: رَبَّنَا وَلَكَ الْحَمْدُ، قَبْلَ أَنْ يَسْجُدَ، ثُمَّ يَقُولُ: اللهُ أَكْبَرُ حِينَ يَهْوِي سَاجِدًا، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْفَعُ رَأْسَهُ مِنَ السُّجُودِ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَسْجُدُ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَرْفَعُ رَأْسَهُ مِنَ السُّجُودِ، ثُمَّ يُكَبِّرُ حِينَ يَقُومُ مِنَ الْجُلُوسِ فِي الِاثْنَتَيْنِ، وَيَفْعَلُ ذَلِكَ فِي كُلِّ رَكْعَةٍ، حَتَّى يَفْرُغَ مِنَ الصَّلَاةِ، ثُمَّ يَقُولُ حِينَ يَنْصَرِفُ: وَالَّذِي نَفْسِي بِيَدِهِ، إِنِّي لَأَقْرَبُكُمْ شَبَهًا بِصَلَاةِ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، إِنْ كَانَتْ هَذِهِ لَصَلَاتَهُ حَتَّى فَارَقَ الدُّنْيَا.

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-:
O maa n kabara nibi gbogbo irun ninu eyi ti o jẹ ọran-anyan ati eyi ti o yatọ si i, ninu Ramadan ati oṣu ti o yatọ si i, o maa n kabara nigba ti o ba dìde, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba rukuu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ pe: Robbanaa wa laKal hamdu, ṣíwájú ki o to forikanlẹ, lẹyin naa o maa n sọ pe: Allahu Akbar nigba ti o ba lọ silẹ ni ẹni ti o forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba forikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba dide lati ijokoo nibi rakah meji naa; o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo rakah, titi o maa fi pari irun, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba ti n lọ pe : Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju emi ni irun mi jọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ju ninu yin, eleyii si ni irun rẹ titi o fi fi aye silẹ.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 803

Àlàyé

Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- gba apakan wa ninu bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n kirun, o wa sọ pe ti o ba fẹ kirun, o maa n kabara nigba ti o ba dide fun kabara wiwọ irun, lẹyin naa o maa n kabara nigba ti o ba n lọ si rukuu, ati nigba ti o ba fẹ forikanlẹ, ati nigba ti o ba gbe ori dide lati iforikanlẹ, ati nigba ti o ba forikanlẹ ni iforikanlẹ ẹlẹẹkeji, ati nigba ti o ba gbe ori rẹ dide kuro nibẹ, ati nigba ti o ba dide lati rakah meji akọkọ lẹyin ti o ba jokoo fun ataya akọkọ nibi irun oni rakah mẹta tabi oni rakah mẹrin, lẹyin naa o maa n ṣe bẹẹ nibi gbogbo irun pata titi o maa fi pari rẹ, o maa n sọ ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu pe: Sami’alloohu liman hamidaHu, lẹyin naa o maa n sọ ti o ba wa ni iduro pe: Robbanaa wa laKal hamdu.
Lẹyin naa Abu Huraira maa n sọ ti o ba ti pari irun pé: Mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, dajudaju ẹmi ni ìrun mi jọ irun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jù, bi o ṣe maa n kirun nìyí titi o fi fi aye silẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Kikabara maa n waye nibi gbogbo lilọ-ilẹ ati lilọ-soke afi nibi gbigbe e soke lati rukuu, o maa sọ nibẹ pe Sami’alloohu liman hamidaHu.
  2. Iko akolekan awọn sahaabe lori kikọṣe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ṣiṣọ sunnah rẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

61 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية