1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”

عن أَبِي حَازِمِ بْن دِينَارٍ:
أَنَّ رِجَالًا أَتَوْا سَهْلَ بْنَ سَعْدٍ السَّاعِدِيَّ، وَقَدِ امْتَرَوْا فِي الْمِنْبَرِ مِمَّ عُودُهُ، فَسَأَلُوهُ عَنْ ذَلِكَ، فَقَالَ: وَاللهِ إِنِّي لَأَعْرِفُ مِمَّا هُوَ، وَلَقَدْ رَأَيْتُهُ أَوَّلَ يَوْمٍ وُضِعَ، وَأَوَّلَ يَوْمٍ جَلَسَ عَلَيْهِ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، أَرْسَلَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِلَى فُلَانَةَ -امْرَأَةٍ من الأنصار قَدْ سَمَّاهَا سَهْلٌ-: «مُرِي غُلَامَكِ النَّجَّارَ أَنْ يَعْمَلَ لِي أَعْوَادًا أَجْلِسُ عَلَيْهِنَّ إِذَا كَلَّمْتُ النَّاسَ»، فَأَمَرَتْهُ فَعَمِلَهَا مِنْ طَرْفَاءِ الْغَابَةِ، ثُمَّ جَاءَ بِهَا، فَأَرْسَلَتْ إِلَى رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَأَمَرَ بِهَا فَوُضِعَتْ هَاهُنَا، ثُمَّ رَأَيْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ صَلَّى عَلَيْهَا وَكَبَّرَ وَهُوَ عَلَيْهَا، ثُمَّ رَكَعَ وَهُوَ عَلَيْهَا، ثُمَّ نَزَلَ الْقَهْقَرَى، فَسَجَدَ فِي أَصْلِ الْمِنْبَرِ ثُمَّ عَادَ، فَلَمَّا فَرَغَ أَقْبَلَ عَلَى النَّاسِ فَقَالَ: «أَيُّهَا النَّاسُ، إِنَّمَا صَنَعْتُ هَذَا لِتَأْتَمُّوا وَلِتَعَلَّمُوا صَلَاتِي».

Lati ọdọ Abu Haazim ọmọ Diinaar:
Dajudaju awọn ọkunrin kan wa ba Sahl ọmọ Sahd As-Saa’idiyy, wọn ṣe iyemeji nipa minbari latara nnkan wo ni igi rẹ ti wa, ni wọn wa bi i leere nipa ìyẹn, ni o wa sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mo mọ latara nnkan ti o ti wa, dajudaju mo ri i ni ọjọ akọkọ ti wọn gbe e kalẹ, ati ọjọ akọkọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jokoo sori rẹ, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si lagbaja- obinrin kan ninu awọn Ansar ti Sahl si ti dárúkọ rẹ-: “Pa ọmọ-ọdọ rẹ ti o jẹ kafinta láṣẹ ki o kan awọn igi kan fun mi ti maa maa jokoo le wọn lori ti mọ ba fẹ ba awọn eniyan sọ̀rọ̀”, ni o wa pa a láṣẹ o si ṣe e latara igi TỌRFAAHU ti o maa n wa nínú igbó, lẹyin naa o gbe e wa, ni o wa ranṣẹ si ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o wa ni ki wọn gbe wọn kalẹ sí ibì kan, lẹyin naa ni mo ri ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o kirun lori rẹ, ti o si kabara nigba ti o wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n fi ẹyin rìn, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari o doju kọ awọn eniyan, ni o wa sọ pe: “Ẹyin ènìyàn, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le tẹle mi ki ẹ si le kọ́ irun kiki mi”.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 917

Àlàyé

Awọn ọkunrin kan wa ba ọkan ninu awọn saabe, ti wọn n bi i leere nipa minbari ti Anabi ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n lo: latara nnkan wo ni wọn ti ṣe e? Wọn ti ba ara wọn jiyan ti wọn ti ba ara wọn fa a lori ìyẹn, ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ranṣẹ si arabinrin kan ninu awọn Ansar ti o ni ọmọ-ọdọ kan ti o jẹ kafinta, o wa sọ fun un pé: Pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati kan minbari kan fun mi ti maa maa jokoo le lori nigba ti mo ba n ba awọn eniyan sọ̀rọ̀, ni arabinrin naa ba da a lohun, o wa pa ọmọ-ọdọ rẹ láṣẹ lati ṣe minbari kan fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara igi ti n jẹ TỌRFAAHU, nigba ti o pari arabinrin naa ba fi ranṣẹ si Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, o ba gbe e wa, ni wọn ba gbe e kalẹ si aaye rẹ ninu mọsalasi, lẹyin naa ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kirun lori rẹ ti o si kabara ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o rukuu ti o si wa lori rẹ, lẹyin naa o sọkalẹ ti o n rin lọ si ẹyin lai yi oju rẹ si ọgangan ẹyin, ni o wa forikanlẹ sibi isalẹ minbari, lẹyin naa o ṣẹri pada, nigba ti o pari irun o dojukọ awọn eniyan, o wa sọ pe: Ẹyin eniyan, dajudaju mo ṣe eyi ki ẹ le maa tẹle mi ki ẹ si kọ irun kiki mi.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe lilo minbari ni nnkan ti a fẹ ati ki oluṣe khutubah gun ori rẹ, ati pe anfaani rẹ ni imu ọrọ de etigbọọ ati ki awọn eniyan le gbọ́ khutubah.
  2. Ṣíṣe kiki irun lori minbari lẹtọọ fun kikọni ni imọ, ati ṣíṣe ki imam ga ju ero ẹyin lọ ti a ba bukaata si i.
  3. Ṣíṣe wiwa iranlọwọ awọn oniṣẹ-ọwọ lẹtọọ nibi awọn bukaata awọn Musulumi.
  4. Ṣíṣe imira kekere lẹtọọ lori irun ti a ba bukaata si i.
  5. Ṣíṣe ki ero ẹyin maa wo Imam rẹ lẹtọọ lori irun; lati le kọ ẹkọ lọdọ rẹ, ati pe dajudaju ìyẹn ko tako irẹlẹ lori irun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

62 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
YAO Yao الياو
KMR Kurmancî الكرمنجية