1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje

عن ابنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما عن النبيِّ صلى الله عليه وسلم قال:
«أُمِرْتُ أَنْ أَسْجُدَ عَلَى سَبْعَةِ أَعْظُمٍ: عَلَى الْجَبْهَةِ وَأَشَارَ بِيَدِهِ عَلَى أَنْفِهِ، وَالْيَدَيْنِ، وَالرُّكْبَتَيْنِ، وَأَطْرَافِ الْقَدَمَيْنِ، وَلَا نَكْفِتَ الثِّيَابَ وَالشَّعَرَ».

Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 812

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun pa a laṣẹ nibi irun ki o fi oríkèé meje ninu awọn oríkèé ara rẹ kan'lẹ; awọn naa ni:
Alakọkọọ: Iwaju ori: Oun ni: Alawẹ oju ti o wa ni oke imu ati oju mejeeji, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, fi ọwọ rẹ si imu rẹ, ti o fihan pe iwaju ati imu jẹ ọkan ninu awọn meje naa, o si tẹnumọ pe ẹni ti o n fi ori kan ilẹ maa fi kan ilẹ pẹlu imu rẹ.
Oríkèé kejì ati ìkẹta: Ọwọ mejeeji.
Ẹlẹẹkẹrin ati Ẹlẹẹkarun-un: Orunkun mejeeji.
Ẹlẹẹkẹfa ati Ẹlẹẹkeje: Awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji.
O si tun pa wa laṣẹ ki a ma so awọn irun wa, ki a si ma ka awọn aṣọ wa papọ nibi iforikanlẹ lati fi da aabo bo o; bi ko ṣe pe a maa da a silẹ titi ti yio fi kan ilẹ, nitori naa yio le'lẹ pẹlu awọn orikee ara naa.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ijẹ dandan fifi ori kan'lẹ pẹlu awọn orikee ara meje ninu irun.
  2. Kikorira lilọ aṣọ ati irun papọ ni ori irun.
  3. O jẹ dandan fun ẹni ti n kirun ki o fi ara balẹ ninu irun rẹ, iyẹn ni pe ki o gbe awọn oríkèé iforikanlẹ meje le ilẹ, ki o si fi ara balẹ lori rẹ titi ti yio fi mu iranti ti wọn ṣe lofin nibẹ wa.
  4. Kikọ kuro nibi lilọ irun jẹ ẹsa fun awọn ọkunrin yatọ si awọn obinrin; nitori pe dajudaju wọn pa obinrin ni aṣẹ pẹlu bibo ara ni ori irun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

59 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية