1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيَّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ -وَكَانَ غَزَا مَعَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ ثِنْتَيْ عَشْرَةَ غَزْوَةً- قَالَ: سَمِعْتُ أَرْبَعًا مِنَ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، فَأَعْجَبْنَنِي، قَالَ:
«لاَ تُسَافِرِ المَرْأَةُ مَسِيرَةَ يَوْمَيْنِ إِلَّا وَمَعَهَا زَوْجُهَا أَوْ ذُو مَحْرَمٍ، وَلاَ صَوْمَ فِي يَوْمَيْنِ: الفِطْرِ وَالأَضْحَى، وَلاَ صَلاَةَ بَعْدَ الصُّبْحِ حَتَّى تَطْلُعَ الشَّمْسُ، وَلاَ بَعْدَ العَصْرِ حَتَّى تَغْرُبَ، وَلاَ تُشَدُّ الرِّحَالُ إِلَّا إِلَى ثَلاَثَةِ مَسَاجِدَ: مَسْجِدِ الحَرَامِ، وَمَسْجِدِ الأَقْصَى، وَمَسْجِدِي هَذَا».

Lati ọdọ Sa‘eed Al-Khuduriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o jẹ ẹni ti o kopa ninu ogun mejila pẹlu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: Mo gbọ nkan mẹẹrin ni ẹnu Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o si jọ mi l'oju, o sọ pe:
«Obinrin ko gbọdọ ṣe irin-ajo ti o to ọjọ meji ayaafi ki ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ o wa pẹlu rẹ, ko si si aawẹ ni ọjọ meji: Itunu awẹ ati ileya, ko si tun si irun lẹyin asunbaa titi ti oorun o fi yọ, ko si si lẹyin Asri naa titi ti yio fi wọ, wọn o si tun gbọdọ di ẹru irin-ajo ayaafi lati lọ si masalasi mẹta: Masalasi abeewọ, ati masalasi aqsa, ati masalasi mi yii».

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 1995

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ kuro nibi awọn alamọri mẹẹrin kan:
Alakọkọọ rẹ: Kikọ fun obinrin kuro nibi ṣiṣe irin-ajo ọjọ meji lai si pẹlu ọkọ rẹ tabi ẹnikan ninu awọn eleewọ rẹ oun naa ni ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ (ọmọbinrin naa) ni eewọ fun un ni ṣiṣe leewọ gbere ninu awọn alasunmọ-ọn, gẹgẹ bii ọmọ ati baba, ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ ọkunrin ati ọmọkùnrin ọmọ-iya rẹ obinrin, ati ọmọ-iya baba rẹ l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya rẹ l'ọkunrin, ati awọn to jọ bẹ́ẹ̀.
Ẹlẹẹkeji rẹ: Kikọ kuro nibi gbigba aawẹ ọjọ ọdun itunu ati ọjọ ọdun ileya, ki baa ṣe pe musulumi gba mejeeji ni gbigba ti ẹ̀jẹ́, tabi aṣegbọrẹ, tabi itanran.
Ẹlẹẹkẹta rẹ: Kikọ kuro nibi kiki irun naafila lẹyin irun Asri titi ti oorun o fi wọ, ati lẹyin yiyọ aarọ titi ti oorun o fi yọ.
Ẹẹkẹrin rẹ: Kikọ kuro nibi ṣiṣe irin-ajo lọ si aaye kan ninu awọn aaye ati nini adisọkan ọla rẹ ati nini adisọkan pe adipele ẹsan wa nibẹ yatọ si awọn masalasi mẹta, nitori naa a ko gbọdọ di ẹru irin-ajo lọ si ibi ti o yatọ si wọn lati lọ kirun nibẹ, torí pé dajudaju adipele o ni maa ba ẹsan ayaafi ni awọn masalasi mẹta yii, masalasi abeewọ (kahbah), ati masalasi Anabi, ati masalasi aqsa.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Aini ẹtọ ṣiṣe irin-ajo obinrin lai si eleewọ pẹlu rẹ.
  2. Obìnrin o kii ṣe eleewọ fun obinrin ni irin-ajo; fun gbolohun rẹ ti o sọ pe: “Ọkọ rẹ tabi eleewọ rẹ”.
  3. Gbogbo nkan ti wọn ba ti n pe ni irin-ajo, dajudaju wọn kọ fun obinrin ki o lọ lai si ọkọ tabi eleewọ pẹlu rẹ, ati pe hadīth yii nii ṣe pẹlu ìṣesí onibeere ati aaye rẹ.
  4. Eleewọ obinrin ni ọkọ rẹ tabi ẹni ti wọn ṣe fifẹ ẹ ni eewọ fun un titi láéláé latari ìbátan gẹgẹ bii baba ati ọmọ ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin ati ọmọ-iya iya l'ọkunrin, tabi ifunlọyan gẹgẹ bii baba lati ibi ifunlọyan ati ọmọ-iya baba l'ọkunrin lati ibi ifunlọyan, tabi ijẹ ana gẹgẹ bii baba ọkọ, ati pe yio jẹ musulumi ti o balaga ti o ni laakaye ti o ṣeé gbara le ti o ṣee fi ọkan tan, torí pé dajudaju nkan ti wọn gbero nibi eleewọ ni dida aabo bo obinrin ati sisọ ọ ati mimu ojú tó alamọri rẹ.
  5. Akolekan ofin Isilaamu pẹlu ọmọbinrin ati dida aabo bo o ati sisọ ọ.
  6. Aini alaafia kiki irun naafila lẹyin irun Al-fajri ati irun Asri, ati pe wọn yọ kuro ninu iyẹn ṣiṣe adapada awọn irun ọranyan ti o bọ, ati awọn irun ti o ni idi gẹgẹ bii tahiyyatul masjid (irun ti a maa n ki ti a ba wọ masalasi ki a to jokoo) ati eyi ti o jọ ọ.
  7. Irun kiki jẹ eewọ ni kete lẹyin yiyọ oorun, dipo bẹ́ẹ̀ o gbọdọ gbera soke ni odiwọn ọ̀kọ̀, ni nkan ti o sunmọ iṣẹju mẹwaa titi di bii iṣẹju mẹẹdogun.
  8. Asiko Asri gun titi di igba ti oorun o fi wọ.
  9. O n bẹ ninu rẹ ṣiṣe ni ẹtọ didi ẹru irin-ajo lọ si awọn masalasi mẹta.
  10. Ọla ti n bẹ fun awọn masalasi mẹtẹẹta naa lori awọn miran.
  11. Ailẹtọọ ṣiṣe irin-ajo lati lọ bẹ saare wo koda ko jẹ saare Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe ṣiṣe abẹwo rẹ (saare Anabi) tọ fun ẹni ti o wa ni Mẹdinah, tabi ẹni ti o wa si ibẹ fun idi kan ti wọn ṣe lofin tabi ti o lẹtọọ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية