1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin

عَن عَبْدِ الرَّحْمَنِ بْنِ أَبِي لَيْلَى أَنَّهُمْ كَانُوا عِنْدَ حُذَيْفَةَ، فَاسْتَسْقَى فَسَقَاهُ مَجُوسِيٌّ، فَلَمَّا وَضَعَ القَدَحَ فِي يَدِهِ رَمَاهُ بِهِ، وَقَالَ: لَوْلاَ أَنِّي نَهَيْتُهُ غَيْرَ مَرَّةٍ وَلاَ مَرَّتَيْنِ -كَأَنَّهُ يَقُولُ: لَمْ أَفْعَلْ هَذَا-، وَلَكِنِّي سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«لاَ تَلْبَسُوا الحَرِيرَ وَلاَ الدِّيبَاجَ، وَلاَ تَشْرَبُوا فِي آنِيَةِ الذَّهَبِ وَالفِضَّةِ، وَلاَ تَأْكُلُوا فِي صِحَافِهَا، فَإِنَّهَا لَهُمْ فِي الدُّنْيَا وَلَنَا فِي الآخِرَةِ».

Lati ọdọ Abdur Rahmān ọmọ Abu Laylā o ni pe awọn wa ni ọdọ Hudhayfah, ni o ba beere fun omi, ni abọná kan ba fun un ni omi, nígbà tí o wa gbe ife omi yẹn fun un, o lẹ ẹ pada mọ ọn, o wa sọ pe: Ti kii ba ṣe pe mo ti kọ ọ fun un ni nkan ti kii ṣe ẹẹkan ti kii ṣe ẹẹmeji - bi ẹni ti n sọ pe: Mio ba ti ṣe nǹkan ti mo ṣe yii -, ṣugbọn mo gbọ ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe:
Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 5426

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun awọn ọkunrin kuro nibi wíwọ asọ alaari pẹlu gbogbo iran rẹ. O si kọ fun awọn obinrin ati ọkunrin kuro nibi jijẹ ati mimu ninu awọn igba ati abọ wura ati fadaka. O si sọ pe ẹsa lo jẹ fun awọn mumini ni ọjọ igbedide; nítorí pé wọn jina si i ni aye lati tẹle aṣẹ Ọlọhun, Amọ awọn keferi ko nii jẹ ti wọn ni ọjọ ikẹyin; nitori pe wọn ti kanju lo awọn nkan igbadun wọn ni ile-aye pẹlu lilo ti wọn lo o, ati ìyapa aṣẹ Ọlọhun wọn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe wiwọ aṣọ alaari ni eewọ fun ọkunrin, ati adehun iya ti o le fun ẹni ti o ba wọ ọ.
  2. Wọn ṣe ni ẹtọ fun awọn obinrin ki wọn wọ aṣọ alaari.
  3. Ṣiṣe jijẹ ati mimu ninu abo wura ati fadaka ati ife wọn ni eewọ fun ọkunrin ati obinrin.
  4. Lile Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - nibi kikọ, o si sọ idi rẹ pe oun ti kọ fun un ni ọpọ igba kuro nibi lilo awọn igba wura ati fadaka, ṣugbọn ko jawọ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية