1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ

عَنْ عَائِشَةَ رضي الله عنها قَالَتْ:
فَقَدْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لَيْلَةً مِنَ الْفِرَاشِ فَالْتَمَسْتُهُ فَوَقَعَتْ يَدِي عَلَى بَطْنِ قَدَمَيْهِ وَهُوَ فِي الْمَسْجِدِ وَهُمَا مَنْصُوبَتَانِ، وَهُوَ يَقُولُ: «اللهُمَّ أَعُوذُ بِرِضَاكَ مِنْ سَخَطِكَ، وَبِمُعَافَاتِكَ مِنْ عُقُوبَتِكَ، وَأَعُوذُ بِكَ مِنْكَ لَا أُحْصِي ثَنَاءً عَلَيْكَ أَنْتَ كَمَا أَثْنَيْتَ عَلَى نَفْسِكَ».

Lati ọdọ Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe:
Mo ṣafẹku ojiṣẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) lori ibusun loru ọjọ kan, mo wa nfi ọwọ wa a kiri bẹẹni ọwọ mi kan inu atẹlẹsẹ rẹ nigbati o wa ni iforikanlẹ, ti o gbe gigisẹ rẹ mejeeji sí oke, ti nsọ bayi ninu adura rẹ pe: "irẹ Ọlọhun mo sa di ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ, mo si sa di amojukuro Rẹ kuro ni bi ijẹ níyà Rẹ". Mo tun sa di irẹ Ọlọhun pẹlu araarẹ, mi o le yin ọ tán gẹlẹ bi o ṣe yin ara Rẹ.

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 486

Àlàyé

Aishah - ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - o sọ bayi pe: mo sun lẹgbẹ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), mo ṣe afẹku rẹ ni oru (mi o ri), mo wa fi ọwọ mi woo ni ààyè ti o ma ti nkirun ninu yàrá, bayi ni mo kan lojiji pe o nkirun lọwọ ti gigisẹ rẹ mejeeji si wa ni iduro, bẹẹ sì ni o nsọ bayi pe:
(mo nwa isọ) mo nṣe atẹgun sọdọ Rẹ (pẹlu ìyọnu Rẹ kuro nibi ibinu Rẹ) sí mi tabi sí awọn ijọ mi, (ati) pe mo nwa isọra (pẹlu amojukuro Rẹ) ati amojukuro re ti o pọ (kuro nibi ijẹniya Rẹ), (mo wa idaabobo lọdọ Rẹ pẹlu araarẹ) ati pẹlu awọn iroyin rirẹwa Rẹ lọdọ awọn iroyin titobi Rẹ, nigbati o jasipe ẹnikan ò lee ṣọ ni lọdọ Rẹ àyaàfi ìwọ fún rara Rẹ, kò sibi aa salọ fún akoyọ, bẹẹ sì ni kò sibi ti a le sadi lati sa fún Ọlọhun ayaafi ki a sadi Ọlọhun, (Mi o le ṣe onka ẹyin fún irẹ Ọlọhun), mi o nikapa, mi o sì lè dé òpin ati onka lati ka gbogbo idẹra Rẹ tan nitori ikagara mi, bẹẹ ni mi o le ka daada Rẹ tan gẹgẹbi O ṣe lẹtọ si i, koda bi mo ba ṣe igbiyanju ati akitiyan láti ṣe bẹẹ, (gẹgẹ bí Irẹ Ọlọhun ṣe ṣe ẹyìn fún ara Rẹ) Iwọ ni O ṣe ẹyìn fún Pàápàá ara Rẹ, ẹyin ti o ba ọ mu, taani ẹni náà tí o ni ikapa lati mu ẹyin Rẹ wá ní bo ṣe yẹ?!

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Fifẹ ki a se awọn adua yii nibi iforikanlẹ
  2. Meirak sọ bayi pe: ninu ọkan ninu awọn ẹgbawa An-Nasaaiy: Anọbi a maa ṣe adua yi ti o ba pari irun rẹ, ti o si fi ẹgbẹ le lẹ láti sun.
  3. Fifẹ ki a se ẹyìn fún Ọlọhun pẹlu awọn iroyin Rẹ ati imáa pe pẹlu awọn orukọ Rẹ ti o f'ẹsẹ rinlẹ nínú Al-kurani ati Sunnah Anọbi.
  4. Igbe Ọlọhun Adẹda ga wà nibẹ nibi itẹriba ati ni iforikanlẹ.
  5. O lẹtọ lati wá isọra (ìdáàbòbò) pẹlu awọn iroyin Ọlọhun, bẹẹ ni o lẹtọ lati wá isọra pẹlu pàápàá Rẹ, mimọ fún Ọlọhun ti O gaju lọ.
  6. Al-Khọtọọbi sọ bayi pe: itumọ ti o lẹ̀ wa ninu ọrọ yii, ohun náà ni pe dájúdájú o ti wá isọra lọdọ Ọlọhun pe ko ṣọ ohun pẹlu ìyọnu Rẹ nibi ibinu Rẹ ati pẹlu amojukuro Rẹ nibi ijẹni-niya Rẹ, ìyọnu ati ibinu ọrọ ati ida keji niwọn (orogun meji niwọn), bẹẹ náà ni amojukuro ati ifi ọwọ iya muni, nigbati o de ibi idarukọ nkan ti ko ni idakeji Oun náà ni Allah (Ọlọhun) mimọ ni fun Ọba ti O ga jù, O wa isọra pẹlu Rẹ lọdọ ara Rẹ, ti kii se ọdọ ẹlòmíràn, ìtumọ eléyun nipe: iwa aforijin nibi aseeto ojúṣe ọranyan o wa ninu ẹto ìjọsìn fun Un ati ifi ẹyìn fun Un. Gbólóhùn rẹ to sọ pe: "mi o lẹ se onka ẹyin fún Ẹ: ìtumọ rẹ ni pé: mi o ni ikapa lati mu dé ogongo ẹyin Rẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

51 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية