1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan

عَنْ ‌أَبِي الزُّبَيْرِ قَالَ:
كَانَ ‌ابْنُ الزُّبَيْرِ يَقُولُ فِي دُبُرِ كُلِّ صَلَاةٍ حِينَ يُسَلِّمُ: «لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَحْدَهُ لَا شَرِيكَ لَهُ، لَهُ الْمُلْكُ وَلَهُ الْحَمْدُ وَهُوَ عَلَى كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ، لَا حَوْلَ وَلَا قُوَّةَ إِلَّا بِاللهِ، لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، ‌وَلَا ‌نَعْبُدُ ‌إِلَّا إِيَّاهُ، لَهُ النِّعْمَةُ وَلَهُ الْفَضْلُ وَلَهُ الثَّنَاءُ الْحَسَنُ، لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ مُخْلِصِينَ لَهُ الدِّينَ وَلَوْ كَرِهَ الْكَافِرُونَ» وَقَالَ: «كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يُهَلِّلُ بِهِنَّ دُبُرَ كُلِّ صَلَاةٍ».

Lati ọdọ Abu Zubayr, o sọ pe:
Ibnu Zubayr jẹ ẹniti o maa n sọ ni ẹyin ìrun kọọkan nigba ti o ba salamọ pe: “Laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharīka lahu, lahul mulku wa lahul hamdu wa huwa ala kulli shay’in qodīr, laa haola walā quwwata illā biLlāh, lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu, lahu ni‘matu wa lahul fadlu wa lahuu thanāhul hasan, lā ilāha illā Allāhu mukhlisiina lahuu dīna wa lao karihal kāfirūna”, o wa sọ pe: «Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan».

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 594

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi asikiri nla yii ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin ti o ba salamọ ni gbogbo irun ọran-anyan, itumọ rẹ si ni pe:
“Lā ilāha illā Allāhu”: Ìyẹn ni pé ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayaafi Allāhu.
“Wahdahu lā sharīka lahu” ìyẹn ni pé: Dajudaju ko si akẹgbẹ fun un nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ.
“Lahul mulku” ìyẹn ni pé: TiRẹ ni ìjọba ti ko ni ààlà ti o kárí, ti o gbòòrò, ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ati ohun ti n bẹ ni àárín méjèèjì.
“Wa lahul hamdu” ìyẹn ni pé: Oun ni Ẹnití a n royin pẹlu pipe ti ko ni ààlà, Ẹni tí a n yin pẹlu pipe ni ti ifẹ ati gbigbe tobi lori gbogbo ìṣesí, nigba idunnu, ati nigba inira.
“Wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr”: Ikapa Rẹ pe ni gbogbo ọna, nnkankan o si da A ni agara ri, alamọri kankan o si soro lati ṣe fun Un ninu awọn alamọri.
“Lā haola walā quwwata illā biLlāh” ìyẹn ni pé: Ko si iyipada kuro nibi ìṣesí kan sí iṣesi miiran, ati kuro nibi ṣiṣẹ Ọlọhun lọ sí titẹle àṣẹ Rẹ, ko si si agbara kankan ayaafi pẹlu Allāhu, Oun ni Olùrànlọ́wọ́, Oun si ni a maa n gbára lé.
“Lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu”: O jẹ ìkànnípá fun itumọ ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin ati íhánnà ẹbọ (mimu orogun mọ Ọlọhun), ati pe ko si ẹnití o lẹtọọ si ijọsin ayaafi Oun.
“Lahu ni‘motu wa lahul fadlu”: Oun ni O n ṣẹda awọn idẹkun ti O ni ikapa rẹ, ti O si maa n fi i da ọla lori ẹnití o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ.
“Wa lahu thanāhul hasan”: Lórí pàápàá Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ, ati lori gbogbo ìṣesí.
“Lā ilāha illā Allāhu, mukhlisiina lahu dīna”: Ìyẹn ni pe ni ẹni ti wọn a maa mu Un ni Ọkan ṣoṣo laisi ṣekarini ati ṣekagbọni nibi titẹle Ọlọhun.
“Wa lao karihal kāfirūna”, ìyẹn ni pe: Ni ẹni tí wọn fi ẹsẹ rinlẹ lori mimu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati jijọsin fun Un, koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. A fẹ́ ki a maa dunni mọ iranti yii lẹyin gbogbo irun ọranyan kọọkan.
  2. Musulumi a maa ṣe iyanran pẹlu ẹsin rẹ yio si tun maa fi awọn arisami rẹ han koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.
  3. Ti gbolohun: “Duburu Sọlaat” ba wa nínú hadiisi, ti nkan ti o wa ninu hadīth yẹn ba jẹ àsíkìrí, ipilẹ rẹ ni ki o jẹ ẹyin salamọ, ti o ba wa jẹ adua, iwaju salamọ ni yio jẹ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

64 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
YAO Yao الياو
KMR Kurmancî الكرمنجية