1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ?

عَنْ عَبْدِ الرَّحْمَنِ بْنِ أَبِي لَيْلَى قَالَ: لَقِيَنِي كَعْبُ بْنُ عُجْرَةَ، فَقَالَ: أَلاَ أُهْدِي لَكَ هَدِيَّةً؟
إِنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ خَرَجَ عَلَيْنَا، فَقُلْنَا: يَا رَسُولَ اللَّهِ، قَدْ عَلِمْنَا كَيْفَ نُسَلِّمُ عَلَيْكَ، فَكَيْفَ نُصَلِّي عَلَيْكَ؟ قَالَ: «فَقُولُوا: اللَّهُمَّ صَلِّ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا صَلَّيْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ، اللَّهُمَّ بَارِكْ عَلَى مُحَمَّدٍ وَعَلَى آلِ مُحَمَّدٍ، كَمَا بَارَكْتَ عَلَى آلِ إِبْرَاهِيمَ، إِنَّكَ حَمِيدٌ مَجِيدٌ».

Lati ọdọ Abdur Rahman ọmọ Abu Laila, o sọ pe: Ka'b ọmọ 'Ujrah pade mi, o sọ pe: Njẹ mi ko nii ta ẹ lọrẹ ọrẹ kan?
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ? o sọ pe: "Ẹ maa sọ pe: Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun, Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 6357

Àlàyé

Àwọn saabe beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un? Lẹyin mimọ bi wọn ṣe maa salamọ fun un nibi ataya: "As salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu...."? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un, ìtumọ̀ rẹ ni pe: "Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin" O túmọ̀ si pe: Ṣe ẹyin fun un pẹlu iranti ti o rẹwa ni ọdọ àwọn malaika, ati fun awọn olutẹle rẹ ninu ẹsin rẹ, ati awọn olugbagbọ ninu awọn alasunmọ rẹ. "ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim" Gẹgẹ bi o ṣe da ọla lori awọn ara ile Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- awọn ni Ibrahim ati Isma'il ati Ishaq ati awọn arọmọdọmọ wọn ati awọn olutẹle wọn ti wọn jẹ olugbagbọ, nitori naa, so ọla Rẹ mọ Muhammad- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "Innaka Hamiidun Majeedun" O n túmọ̀ si pe: Ọba ti a n gbe ẹyin fun nibi paapaa Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ, Ọba ti O gbòòrò nibi titobi Rẹ ati àṣẹ Rẹ ati ọrẹ Rẹ. "Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim" O n túmọ̀ si pe: Fun un ninu oore ati apọn-ọnle eyi ti o tobi julọ ninu rẹ, ki o si ṣe alekun rẹ ki o si fi i rinlẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn ẹni ìṣáájú wọn maa n fun ara wọn ni ẹbun àwọn ọ̀rọ̀ imọ.
  2. Jijẹ dandan ṣiṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi ataya igbẹyin nibi irun.
  3. Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi titọrọ ikẹ ati ọla fun un mọ awọn saabe rẹ.
  4. Ọna yii ni o pe julọ ninu awọn ọna ti o wa nibi ṣíṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية