عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«كُلُّ سُلاَمَى مِنَ النَّاسِ عَلَيْهِ صَدَقَةٌ، كُلَّ يَوْمٍ تَطْلُعُ فِيهِ الشَّمْسُ يَعْدِلُ بَيْنَ الِاثْنَيْنِ صَدَقَةٌ، وَيُعِينُ الرَّجُلَ عَلَى دَابَّتِهِ فَيَحْمِلُ عَلَيْهَا أَوْ يَرْفَعُ عَلَيْهَا مَتَاعَهُ صَدَقَةٌ، وَالكَلِمَةُ الطَّيِّبَةُ صَدَقَةٌ، وَكُلُّ خُطْوَةٍ يَخْطُوهَا إِلَى الصَّلاَةِ صَدَقَةٌ، وَيُمِيطُ الأَذَى عَنِ الطَّرِيقِ صَدَقَةٌ».

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
Gbogbo ibi ti àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara ọmọniyan ni saara jẹ dandan le e lori nibẹ, gbogbo ọjọ ti oorun ba ti n yọ ti o ba n ṣe deede laarin eeyan meji saara ni, ati pe ki o ran ẹnikan lọwọ l'ori nkan ọ̀gùn rẹ, boya ki o gbe e gun un tabi ki o gbe ẹru rẹ fun un lori rẹ saara ni, ati pe ọrọ daadaa saara ni, ati gbogbo igbesẹ ti o ba n gbe lọ sí ibi irun saara ni, ki o si tun maa mu nkan ti o le ṣe eeyan ni ṣuta kuro l'ọna saara ni»

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 2989

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju o jẹ dandan l'ori gbogbo musulumi ti o ni iwọ ni ọrùn ni ojoojumọ pẹlu onka gbogbo ibi tí àwọn eegun ti pàdé pọ ni ara rẹ lati maa ṣe saara, ti yio ṣe e fun Ọlọhun lati fi dupẹ alaafia, ati pe o ṣe awọn ibi ipadepọ àwọn eegun rẹ ni nkan ti o jẹ ki o rọrun fun un lati ka a kò ati lati nà án, Ati pe dajudaju saara yẹn yio maa jẹ ṣiṣe pẹlu gbogbo iṣẹ daadaa patapata, ko si mọ nibi ifunni ni owo nikan, ninu rẹ naa sì ni: Deede rẹ ati atunse rẹ laarin awọn onija meji saara ni, Ati pe saara n bẹ nibi iranlọwọ rẹ fun ẹni ti o kagara nibi nkan ọ̀gùn rẹ ti waa wa gbe e gun un tabi ki o na ọwọ ẹru rẹ fún un, Ati pe ọrọ ti o daa bii iranti ati adua ati salamọ ati eyi ti o yatọ si i saara ni, Ati pe gbogbo igbesẹ kọọkan ti o ba n gbe lọ s'ibi irun saara ni, Ati pe mimu nkan ti o le ṣeni ni ṣuta kuro l'ọna saara ni.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Tito awọn eegun ọmọ Anabi Ādam ati ini alaafia rẹ ninu awọn idẹra Ọlọhun ti o tobi julọ lori rẹ ni, nitori naa eegun kọọkan bukaata si saara fun un lati dupẹ idẹra yẹn.
  2. Ṣiṣenilojukokoro lori títún ọpẹ dú ni ojoojumọ fun aiduro awọn idẹra yẹn.
  3. Ṣiṣenilojukokoro lori idunimọ awọn naafila ati saara ni ojoojumọ.
  4. Ọla ti nbẹ fun ṣiṣe àtúnṣe laarin awọn eeyan.
  5. Ṣiṣenilojukokoro lori ki ọmọniyan maa ran ọmọ-iya rẹ lọwọ; torí pé iranlọwọ rẹ fun un saara ni.
  6. Ṣiṣenilojukokoro lori kiki janmọọn ati ririn lọ síbẹ̀, ati yiye awọn masalasi pẹlu ìyẹn.
  7. Ijẹ dandan ṣiṣe apọnle awọn oju-ọna awọn musulumi pẹlu jijina si nkan ti o le ṣe wọn ni ṣuta tabi ko inira ba wọn.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

62 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو