1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi “Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”

عن ابن عمر رضي الله عنهما قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«مَا زَالَ يُوصِينِي جِبْرِيلُ بِالْجَارِ، حَتَّى ظَنَنْتُ أَنَّهُ سَيُوَرِّثُهُ».

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Jibril kò yẹ̀ kò gbò ni ẹni tí n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun mi nipa aládùúgbò, titi ti mo fi lérò pé yoo mu u jogún”.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 6014

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe Jibril ko yẹ ni ẹni tí n pààrà fun un ti o si n pa a láṣẹ láti ni akolekan aládùúgbò ti ilé rẹ sunmọ, Mùsùlùmí ni tabi Kèfèrí, mọlẹbi ni tabi ẹni tí kii ṣe mọ̀lẹ́bí, pẹlu ṣiṣọ iwọ̀ rẹ, ki eeyan ma si fi suta kan an, ki èèyàn si maa ṣe daadaa si i, ki èèyàn si maa ṣe suuru lori suta rẹ, titi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi lérò pe imisi maa sọ̀kalẹ̀ pé ki a maa fun un ninu dúkìá aládùúgbò rẹ ti o ba fi silẹ lẹ́yìn iku rẹ latara bi o ṣe bàbàrà iwọ̀ rẹ, ati bi Jibril ṣe n pààrà rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi ẹtọ ti aládùúgbò ati ọranyan lati ṣe akiyesi iyẹn.
  2. Títẹnu mọ́ ẹ̀tọ́ aládùúgbò pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ n béèrè fun pé kí a bọ̀wọ̀ fún un, ki a wa ki o nífẹ̀ẹ́ ẹni, ki a si ṣe daadaa si i, ki a si ma jẹ ki o ri ìpalára, ki a si maa bẹ ẹ wo ti o ba ṣe àìsàn, ki a si maa ki i nígbà ìdùnnú, ki a si ba a kẹ́dùn nígbà àjálù.
  3. Bí ẹnu-ọ̀nà aládùúgbò bá ṣe sunmọ si, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀tọ́ rẹ̀ ṣe maa kanpá sí.
  4. Pípé sharia nibi nǹkan ti o mu wa ninu nǹkan ti didara àwùjọ wa nínú ẹ, bii ṣíṣe dáadáa si awọn aládùúgbò, ati titi ìpalára kuro fun wọn.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

68 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
FF Fulfulde Ti èdè Fulani
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
EL Ελληνικά اليونانية
AK Akan الأكانية
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
LN Lingala اللينجالا
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
RN Kirundi الكيروندي
YAO Yao الياو
KMR Kurmancî الكرمنجية