1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ

عَنْ عَبْدِ اللهِ بنِ مَسْعُودٍ رضي الله عنه قال:
سَأَلْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: أَيُّ الذَّنْبِ أَعْظَمُ عِنْدَ اللهِ؟ قَالَ: «أَنْ تَجْعَلَ لِلهِ نِدًّا وَهُوَ خَلَقَكَ» قُلْتُ: إِنَّ ذَلِكَ لَعَظِيمٌ، قُلْتُ: ثُمَّ أَيُّ؟ قَالَ: «وَأَنْ تَقْتُلَ وَلَدَكَ؛ تَخَافُ أَنْ يَطْعَمَ مَعَكَ» قُلْتُ: ثُمَّ أَيُّ؟ قَالَ: «أَنْ تُزَانِيَ حَلِيلَةَ جَارِكَ».

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ" mo sọ pe: Dajudaju ìyẹn tobi, mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o pa ọmọ rẹ; ti o n bẹru ki o maa jẹun pẹlu rẹ" mo sọ pe: Lẹyin naa èwo tún ni? O sọ pe: "Ki o ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣìná".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 4477

Àlàyé

Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere nipa eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ, ó wa sọ pe: Eyi ti o tobi julọ ninu wọn ni ẹbọ ńlá, oun ni ki o wa akẹgbẹ tabi afijọ fun Ọlọhun nibi ijẹ Ọlọhun Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ, ati pe ẹṣẹ yìí, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii ṣe aforijin rẹ afi pẹlu ironupiwada, ti ẹni ti o ba ṣe e ba ku, o maa ṣe gbere ninu ina. Lẹyin naa, ki ọmọniyan pa ọmọ rẹ ni ti ipaya pe ki o maa jẹun pẹlu rẹ, ati pe pipa ẹmi jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni ti wọn pa ba jẹ mọlẹbi ẹni ti o pa ènìyàn, ẹṣẹ rẹ maa tobi bakannaa nigba ti o ba ṣe pe erongba ẹni ti o pa eniyan naa ba pa a nitori ipaya ki ẹni ti wọn pa ma baa ba pin ninu arisiki Ọlọhun. Lẹyin naa, ki ọkùnrin ba iyawo ara adugbo rẹ ṣe ṣina, bii ki o gbiyanju lati tan iyawo ara adugbo rẹ titi o fi maa ba a ṣe ṣina ti yoo si gbà fun un, Ati pe ṣina jẹ eewọ, ṣùgbọ́n ẹṣẹ rẹ maa tobi ti ẹni tí wọ́n bá ṣe ṣina ba jẹ iyawo ara adugbo ti Sharia pàṣẹ ṣíṣe daadaa si i ati wiwu iwa daadaa si i ati biba a lo lọna ti o daa.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijuralọ awọn ẹṣẹ nibi títóbi, gẹgẹ bi awọn iṣẹ oloore naa ṣe maa n ju ara wọn lọ nibi ọla.
  2. Eyi ti o tobi julọ ninu awọn ẹṣẹ ni: Imu orogun pọ mọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, lẹyin naa pipa ọmọ nitori ipaya ki o maa jẹun pẹlu rẹ, lẹyin naa ki o ṣe ṣina pẹlu iyawo ara adugbo rẹ.
  3. Arisiki wa lọwọ Ọlọhun, Ọlọhun- mimọ ni fun Un- si ti mu ìpèsè arisiki awọn ẹda da wa lójú.
  4. Titobi iwọ ara adugbo, ati pe dajudaju fifi suta kan an tobi ni ti ẹṣẹ ju fifi suta kan ẹni ti o yàtọ̀ si i lọ.
  5. Aṣẹda ni Ẹni ti O lẹtọọ si ijọsin ni Oun nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

60 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية