1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Fik'hu ati ìpìlẹ̀ rẹ

Hadiisi Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)

عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤْمِنِينَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهَا أَنَّهَا قَالَتْ:
يَا رَسُولَ اللَّهِ، نَرَى الجِهَادَ أَفْضَلَ العَمَلِ، أَفَلاَ نُجَاهِدُ؟ قَالَ: «لَا، لَكُنَّ أَفْضَلُ الجِهَادِ: حَجٌّ مَبْرُورٌ».

Lati ọdọ Āisha iya àwọn mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a n ri pe jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ni iṣẹ ti o lọla julọ, ṣe aa nii jagun ni? O sọ pe: «Rara, ṣugbọn jihad (ijagun si oju-ọna Ọlọhun) ti o lọla julọ ni: hajj ti o mọ kanga (ti o jẹ atẹwọgba)».

O ni alaafia Bukhaariy gba a wa Sọhiihu ti Bukhaariy - 1520

Àlàyé

Awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - maa n ri ijagun si oju-ọna Ọlọhun ati biba awọn ọta ja ni iṣẹ ti o fi n lọla julọ, Ni Āisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe ṣe awọn naa o nii jagun ni?
Ni o wa juwe wọn - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – lọ sí ibi jihad ti o lọla julọ fun wọn, oun naa ni hajj atẹwọgba (ti o mọ kanga) eleyii ti o ṣe deedee tira Ọlọhun ati sunnah Anabi, ti o si tun la kuro nibi ẹṣẹ ati ṣekarimi.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Jijagun sí oju-ọna Ọlọhun ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fún awọn ọkunrin lo wa.
  2. Hajj lọla fun awọn obinrin ju jijagun lọ, ati pe o wa ninu awọn iṣẹ ti o lọla julọ fun wọn.
  3. Awọn iṣẹ maa n ni ọla ju ara wọn lọ ni ibamu si oṣiṣẹ.
  4. O pe hajj ni jihad; nítorí pé ijagun ẹmi ni, o sì tun ko inawo sinu, ati agbara ti ara, nitori naa o jẹ ijọsin ara ati owo gẹgẹ bii jijagun sí oju-ọna Ọlọhun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية