1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi “Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?”

عن أبي بكرة رضي الله عنه قال: قال النبي صلى الله عليه وسلم:
«‌أَلَا ‌أُنَبِّئُكُمْ بِأَكْبَرِ الْكَبَائِرِ؟» ثَلَاثًا، قَالُوا: بَلَى يَا رَسُولَ اللهِ، قَالَ: «الْإِشْرَاكُ بِاللهِ، وَعُقُوقُ الْوَالِدَيْنِ» وَجَلَسَ وَكَانَ مُتَّكِئًا، فَقَالَ: «أَلَا وَقَوْلُ الزُّورِ»، قَالَ: فَمَا زَالَ يُكَرِّرُهَا حَتَّى قُلْنَا: لَيْتَهُ سَكَتَ.

Lati ọdọ Abu Bakra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
“Njẹ emi ko wa ni fun yin ni iro nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ ńlá bi?” O sọ bẹẹ ni igba mẹ́ta, wọn sọ pe: A fẹ bẹẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o sọ pe: “Mimu orogun pẹ̀lú Ọlọhun ati yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji”, o wa jokoo, o si jẹ ẹni ti o rọgbọku tẹlẹ, ni o wa sọ pe: “Ẹ gbọ o, ati ọrọ eke”, o sọ pe: Ko wa yẹ ni ẹni ti n wi i ni awitunwi titi ti a fi sọ pe: Iba tiẹ si dakẹ.

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 2654

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba - n sọ fun awọn saabe rẹ nipa awọn ti o tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nitori naa o darukọ àwọn mẹta yii:
1. Imu orogun pọ mọ Ọlọhun: Oun naa ni fifi iran kan ninu awọn iran ijọsin fun ẹlòmíràn yatọ si Ọlọhun, ati fifi ẹni ti o yatọ si Ọlọhun dọgba pẹlu Ọlọhun nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ ati awọn iroyin Rẹ.
2. Yiyapa aṣẹ awọn obi mejeeji: Oun naa ni gbogbo ipalara ṣiṣe si obi mejeeji, yala ninu ọrọ tabi iṣe, ati gbigbe ṣiṣe daadaa si wọn jù silẹ.
3. Ọrọ eke, ninu rẹ naa ni ẹri eke: Oun naa ni gbogbo ọrọ irọ ti wọn n fẹ lati fi tabuku ẹni ti o ba ṣẹlẹ si i, pẹlu gbígba dúkìá rẹ, tabi titayọ aala lori ọmọluabi rẹ tabi nkan ti o jọ bẹẹ.
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti paara ikilọ kuro nibi ọrọ eke, lati ṣe itaniji lori ibajẹ rẹ (aidara rẹ) ati oripa aburu rẹ lori awujọ, titi ti awọn saabe fi sọ pe: Ko ba tiẹ si dakẹ; ni ti ìkáàánú rẹ, ati ikorira ohun ti o n yọ ọ lẹnu.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ẹṣẹ ti o tobi julọ ni mimu orogun mọ Ọlọhun; nitori pé O ṣe e ni eyi ti o gba iwaju ti o si tobi ju ninu awọn ẹṣẹ nla, nkan ti o n fi idi eleyii mulẹ ni gbólóhùn Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe {Dájúdájú Allāhu kò níí foríjin (ẹni tí) ó bá ń ṣẹbọ sí I. Ó sì máa ṣàforíjìn fún ohun mìíràn yàtọ̀ sí ìyẹn fún ẹni tí Ó bá fẹ́.}.
  2. Titobi awọn ẹtọ awọn obi mejeeji, latari pe Ọlọhun ti ọla Rẹ ga so ẹtọ wọn mọ ẹtọ ti Ẹ.
  3. Awọn ẹṣẹ pin si awọn ẹṣẹ nla ati awọn ẹṣẹ kekere, ati pe awọn ẹṣẹ nla ni: Gbogbo ẹṣẹ ti o ni ijiya ni aye, gẹgẹ bii awọn ijiya to ni odiwọn ati ègún, tabi adehun iya ọjọ ikẹhin, gẹgẹ bii adehun iya pẹlu wiwọ ina, ati pe awọn ẹṣẹ ti o tobi ipele ipele ni, ti apakan rẹ si nipọn nibi ṣíṣe ni eewọ ju apakan lọ, ati pe awọn ẹṣẹ kekere ni awọn ti o yatọ si awọn ẹṣẹ nla.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

63 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
BG Български البلغارية
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
YAO Yao الياو
KMR Kurmancî الكرمنجية