1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«لَا تَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ حَتَّى تُؤْمِنُوا، وَلَا تُؤْمِنُوا حَتَّى تَحَابُّوا، أَوَلَا أَدُلُّكُمْ عَلَى شَيْءٍ إِذَا فَعَلْتُمُوهُ تَحَابَبْتُمْ؟ أَفْشُوا السَّلَامَ بَيْنَكُمْ».

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹ ko lee wọ alujanna titi ti ẹ fi maa gbagbọ, ati pe e ko lee gbagbọ titi ti ẹ fi máa nífẹ̀ẹ́ ara yin, ẹ wa jẹ ki n juwe yin si nkankan ti o jẹ pe ti ẹ ba ṣe e ẹ máa nífẹ̀ẹ́ ara yin? Ẹ maa tan salamọ ka laarin ara yin».

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 54

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ẹnikankan o lee wọ alujanna ayaafi muumini, ati pe igbagbọ o lee pe ati pe ìṣesí awujọ musulumi o lee daa titi ti wọn o fi nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa juwe lọ sibi eyiti o lọla julọ ninu awọn alamọri eyiti o ṣe pe pẹlu rẹ ni ifẹ fi maa n kari, oun naa ni fifọn salamọ ka laarin awọn musulumi, eleyii ti Ọlọhun ṣe ni kiki fun awọn ẹru Rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Wíwọ al-jannah ko lee maa bẹ ayaafi pẹlu igbagbọ.
  2. Ninu pipe igbagbọ ni ki musulumi o fẹ fun ọmọ ìyá rẹ nkan ti o n fẹ fun ara rẹ.
  3. Ṣiṣe fifọn salamọ ka ati wiwi i fún àwọn musulumi ni ẹtọ; latari nkan ti o wa nibẹ ni fifọn ifẹ ati ifọkanbalẹ ka laarin awọn eeyan.
  4. A ko ki n salamọ ayaafi si musulumi; fún ọrọ rẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o sọ pe: "laarin yin".
  5. O n bẹ nibi imaa salamọ mimu ikọyinsi-ara-ẹni ati ibaraẹni-yan-odi ati ikunsinu kuro.
  6. Pataki ifẹ laarin awọn Musulumi ati pe dajudaju ninu pipe igbagbọ lo wa.
  7. O wa ninu hadīth miran pe dajudaju gbolohun salamọ ti o pe ni: "As salaamu alaykum wa rahmotuLloohi wabarakātuHu", a ti pe o ti to ki a sọ pe: "As salaamu alaykum ".

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية