1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«مَنْ دَعَا إِلَى هُدًى كَانَ لَهُ مِنَ الْأَجْرِ مِثْلُ أُجُورِ مَنْ تَبِعَهُ، لَا يَنْقُصُ ذَلِكَ مِنْ أُجُورِهِمْ شَيْئًا، وَمَنْ دَعَا إِلَى ضَلَالَةٍ كَانَ عَلَيْهِ مِنَ الْإِثْمِ مِثْلُ آثَامِ مَنْ تَبِعَهُ، لَا يَنْقُصُ ذَلِكَ مِنْ آثَامِهِمْ شَيْئًا».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn, ati pe ẹni ti o ba pepe lọ si ibi anu, iru awọn ẹṣẹ ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹṣẹ, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn".

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 2674

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o fi eniyan mọna ti o si tọka ti o si ṣe awọn eniyan lojukokoro lọ sibi oju ọna kan ti ododo ati daadaa n bẹ nibẹ pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹsan ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu ẹsan olutẹle náà. Ati pe ẹni ti o ba dari ti o si tọka awọn eniyan lọ sibi oju ọna ibajẹ ati aburu, ti ẹṣẹ ati àṣìṣe tabi ti àlámọ̀rí ti ko lẹtọọ n bẹ nibẹ, pẹlu ọrọ tabi iṣẹ, iru ẹṣẹ ẹni ti o tẹle e n bẹ fun un laisi pe ìyẹn maa din nnkan kan ku ninu awọn ẹṣẹ wọn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi imọna, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe naa, iru ẹsan ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un, ati pe ìyẹn wa ninu titobi ọla Ọlọhun ati pipe ọrẹ Rẹ.
  2. Ewu ti o n bẹ fun ipepe lọ sibi anu, o kere ni tabi o tobi, ati pe dajudaju olupepe náà, iru ẹṣẹ ẹni ti o siṣẹ n bẹ fun un.
  3. Ẹsan wa ninu iran iṣẹ, ẹni ti o ba pepe lọ sibi dáadáa, iru ẹsan ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un, ẹni ti o ba si pepe lọ sibi aburu, iru ẹṣẹ ẹni ti o ṣe e n bẹ fun un.
  4. O jẹ dandan fun Musulumi lati ṣọ́ra ki wọn ma baa wo o kọṣe pẹlu dida ẹṣẹ rẹ ni gbangba, ti awọn eniyan si n ri i, nitori pe yoo maa da ẹṣẹ pẹlu ẹni ti o ba kọṣe rẹ, koda ki o ma ṣe e lojukokoro lori ìyẹn.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية