1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan

عَنْ أَبِي مُسْلِمٍ الْخَوْلَانِيِّ، قَالَ: حَدَّثَنِي الْحَبِيبُ الْأَمِينُ، أَمَّا هُوَ فَحَبِيبٌ إِلَيَّ، وَأَمَّا هُوَ عِنْدِي فَأَمِينٌ، عَوْفُ بْنُ مَالِكٍ الْأَشْجَعِيُّ رضي الله عنه قَالَ:
كُنَّا عِنْدَ رَسُولِ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، تِسْعَةً أَوْ ثَمَانِيَةً أَوْ سَبْعَةً، فَقَالَ: «أَلَا تُبَايِعُونَ رَسُولَ اللهِ؟» وَكُنَّا حَدِيثَ عَهْدٍ بِبَيْعَةٍ، فَقُلْنَا: قَدْ بَايَعْنَاكَ يَا رَسُولَ اللهِ، ثُمَّ قَالَ: «أَلَا تُبَايِعُونَ رَسُولَ اللهِ؟» فَقُلْنَا: قَدْ بَايَعْنَاكَ يَا رَسُولَ اللهِ، ثُمَّ قَالَ: «أَلَا تُبَايِعُونَ رَسُولَ اللهِ؟» قَالَ: فَبَسَطْنَا أَيْدِيَنَا وَقُلْنَا: قَدْ بَايَعْنَاكَ يَا رَسُولَ اللهِ، فَعَلَامَ نُبَايِعُكَ؟ قَالَ: «عَلَى أَنْ تَعْبُدُوا اللهَ وَلَا تُشْرِكُوا بِهِ شَيْئًا، وَالصَّلَوَاتِ الْخَمْسِ، وَتُطِيعُوا -وَأَسَرَّ كَلِمَةً خَفِيَّةً- وَلَا تَسْأَلُوا النَّاسَ شَيْئًا» فَلَقَدْ رَأَيْتُ بَعْضَ أُولَئِكَ النَّفَرِ يَسْقُطُ سَوْطُ أَحَدِهِمْ، فَمَا يَسْأَلُ أَحَدًا يُنَاوِلُهُ إِيَّاهُ.

Lati ọdọ Abu Muslim Al-Khaolaaniy, o sọ pe: Al-Habeeb Al-Ameen sọ fun mi, ṣùgbọ́n ẹni ti mo nífẹ̀ẹ́ si ni, ṣùgbọ́n oun lọdọ mi, o jẹ olufọkantan, 'Awf ọmọ Maalik Al-'Ashja'iiy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
A jẹ lọdọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, mẹ́sàn-án tabi mẹjọ tabi meje, o wa sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A si ṣẹṣẹ ṣe adehun kan tan ni, a sọ pe: A ti ṣe adehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lẹyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" A sọ pé: Dajudaju a ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, leyin naa, o sọ pe: "Ẹ tẹti ẹ gbọ, njẹ ẹ ko nii ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun?" O sọ pe: A wa tẹ awọn ọwọ wa, a si sọ pé: A ti ṣadehun fun ẹ irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan" dajudaju mo ti ri awọn kan ninu awọn ẹni yẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii ni ki ẹni kankan o ba oun mu un.

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 1043

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa lọdọ awọn kan ninu saabe, o wa beere lọwọ wọn lẹẹmẹta lati ṣadehun fun un lori idunnimọ awọn àlámọ̀rí kan:
Akọkọ: Ijọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo pẹlu mimu awọn àṣẹ Rẹ ṣẹ ati jijina si awọn nnkan ẹkọ Rẹ, ati pe wọn ko gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn.
Ikeji: Gbigbe awọn irun maraarun-un ti a ṣe wọn ni ọran-anyan duro ni ọsan ati oru.
Ikẹta: Gbigbọ ati Itẹle pẹlu daadaa fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn Musulumi.
Ikẹrin: Mimaa sọ gbogbo awọn bukaata wọn kalẹ ti Ọlọhun laini beere nnkan kan nibẹ lọwọ awọn eniyan, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa rẹ ohun rẹ nilẹ pẹlu rẹ.
Dajudaju awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- ṣiṣẹ pẹlu nnkan ti wọn ṣe adehun le lori, titi ẹni ti o gba hadiisi naa fi sọ pe: Dajudaju mo ri awọn kan ninu awọn saabe wọnyẹn, ti ọrẹ ẹnikan ninu wọn ba jabọ, ko nii sọ fun ẹni kankan ki o ba òun mu u, bi ko ṣe pe o maa sọkalẹ ti o si maa mu u fun ara rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣisẹnilojukokoro lori gbigbe bibi awọn eniyan leere ju silẹ, ati jijina si gbogbo nnkan ti wọn n pe ni ibeere, ati rirọrọ kuro lọdọ awọn eniyan koda ki o jẹ nibi àlámọ̀rí ti o kere.
  2. Ibeere ti a kọ kuro nibẹ ni: Ibeere ti o so pọ mọ awọn àlámọ̀rí ti aye, ko de ibi ibeere nipa imọ tabi awọn àlámọ̀rí ẹsin.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

58 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية