1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka

عَنِ ابْنِ عُمَرَ رضي الله عنهما أَنَّ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«أُمِرْتُ أَنْ أُقَاتِلَ النَّاسَ حَتَّى يَشْهَدُوا أَنْ لاَ إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَأَنَّ مُحَمَّدًا رَسُولُ اللَّهِ، وَيُقِيمُوا الصَّلاَةَ، وَيُؤْتُوا الزَّكَاةَ، فَإِذَا فَعَلُوا ذَلِكَ عَصَمُوا مِنِّي دِمَاءَهُمْ وَأَمْوَالَهُمْ إِلَّا بِحَقِّ الإِسْلاَمِ، وَحِسَابُهُمْ عَلَى اللَّهِ».

Lati ọdọ Ibnu Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka, ti wọn ba ṣe iyẹn, wọn ti daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn kuro lọdọ mi afi pẹlu ẹtọ Isilaamu, ati pe ìṣirò iṣẹ wọn wa lọwọ Ọlọhun".

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Bukhaariy - 25

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju Ọlọhun pa oun láṣẹ pẹlu biba awọn ọṣẹbọ ja titi wọn fi maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti a le jọsin fun pẹlu ẹtọ afi Allahu nikan ṣoṣo ti ko si orogun fun Un, ati ki wọn jẹrii ìránṣẹ́ fun Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ati ṣiṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti ijẹrii yii n beere fun bii sisọ awọn irun maraarun-un ni ọsan ati alẹ, ati ki wọn maa yọ saka ti o jẹ ọran-anyan fun awọn ti wọn lẹtọọ si i. Ti wọn ba ti ṣe awọn alamọri yii, dajudaju Isilaamu maa daabo bo awọn ẹjẹ wọn ati awọn dukia wọn, ti pipa wọn ko nii lẹtọọ afi ti wọn ba wu iwa ọdanran kan ti wọn wa maa fi lẹtọọ si pipa lori rẹ tori okùnfà idajọ Isilaamu, lẹyin naa, ni ọjọ igbedide Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa ṣe amojuto ìṣirò iṣẹ wọn nigba ti O mọ awọn kọ̀kọ̀ wọn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn idajọ, dajudaju o maa n lọ lori awọn nnkan ti wọn hàn, ati pe Ọlọhun lo maa n ṣe amojuto awọn kọkọ.
  2. Pataki ipepe lọ sibi imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo, ati pe o jẹ nnkan ti wọn maa n bẹrẹ pẹlu rẹ ninu ipepe.
  3. Hadiisi yii ko túmọ̀ si jíjẹ awọn ọṣẹbọ nipa lori wiwọ inu Isilaamu, bi ko ṣe pe wọn ni igbalaaye lati ṣẹsa laaarin wiwọ inu Isilaamu tabi sisan isakọlẹ; ti wọn ba kọ afi pe ki wọn kọ ipepe sinu Isilaamu, ko si nnkan ti o ku ju biba wọn ja lọ ní ìbámu si awọn idajọ Isilaamu.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

63 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
FR Français Èdè Faransé
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
DA Dansk الدنماركية
RN Kirundi الكيروندي
KMR Kurmancî الكرمنجية
MS Bahasa Melayu الملايو