1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini

عَنْ صُهَيْبٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«عَجَبًا لِأَمْرِ الْمُؤْمِنِ، إِنَّ أَمْرَهُ كُلَّهُ خَيْرٌ، وَلَيْسَ ذَاكَ لِأَحَدٍ إِلَّا لِلْمُؤْمِنِ، إِنْ أَصَابَتْهُ سَرَّاءُ شَكَرَ، فَكَانَ خَيْرًا لَهُ، وَإِنْ أَصَابَتْهُ ضَرَّاءُ صَبَرَ، فَكَانَ خَيْرًا لَهُ».

Lati ọdọ Suhayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini, ti idunu ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ, ti yio si jẹ oore fun un, ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru, ti yio si tun jẹ oore fun un».

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 2999

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe eemọ nipa ọrọ mumini ati awọn iṣesi rẹ ni ti daadaa; ìyẹn ni pe gbogbo ìṣesí rẹ patapata ni oore, ti ìyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini; Ti daadaa ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ fun Ọlọhun lori rẹ; ti yio si gba ẹsan pẹlu ọpẹ dida, Ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru ti yio si tun retí ẹsan lọdọ Ọlọhun, ti yio si tun gba ẹsan suuru, nitori naa inu ẹsan ni o wa ni gbogbo ìṣesí rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti n bẹ fun imaa dupẹ lori idunnu ati ṣiṣe suuru lori inira, ati pe ẹni ti o ba ṣe ìyẹn yio ri ẹsan aye ati ọjọ ikẹyin, ati pe ẹni ti ko ba dupẹ lori idẹra, ti ko sì ṣe suuru lori adanwo, ẹsan ti bọ fun un, ti ẹṣẹ si ti wa fun un.
  2. Ọla ti n bẹ fun igbagbọ, ati pe dajudaju gbigba ẹsan nibi gbogbo ìṣesí ko si fun ẹnikankan ayaafi awọn onigbagbọ.
  3. Idupẹ nigba idunnu ati ṣiṣe suuru lori adanwo ninu awọn iwa awọn olugbagbọ ni o wa.
  4. Nini igbagbọ si akọsilẹ Ọlọhun ati kadara Rẹ yio maa jẹ ki mumini o maa yọnu tan yan-an-yan lori gbogbo ìṣesí rẹ, yatọ si ẹni ti kii ṣe mumini ti yio maa binu ni gbogbo igba nígbà tí inira ba ṣẹlẹ si i, ti o ba tun ri idẹra lati ọdọ Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn yio ko airoju pẹlu rẹ kuro nibi itẹle aṣẹ Ọlọhun, ka mai tii sọ lilo o sibi ìyapa Ọlọhun.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية