1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ

Hadiisi Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a

عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيِّ رضي الله عنه أَنَّهُ سَمِعَ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِذَا رَأَى أَحَدُكُمُ الرُّؤْيَا يُحِبُّهَا فَإِنَّهَا مِنَ اللَّهِ، فَلْيَحْمَدِ اللَّهَ عَلَيْهَا وَلْيُحَدِّثْ بِهَا، وَإِذَا رَأَى غَيْرَ ذَلِكَ مِمَّا يَكْرَهُ، فَإِنَّمَا هِيَ مِنَ الشَّيْطَانِ، فَلْيَسْتَعِذْ مِنْ شَرِّهَا، وَلاَ يَذْكُرْهَا لِأَحَدٍ، فَإِنَّهَا لَنْ تَضُرَّهُ».

Lati ọdọ baba Sa'eed Al-khudiriy - Ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - Ó ní oun gbọ́ tí Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa ba - tí ńsọ bayii pé:
"Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a".

O ni alaafia Bukhaariy gba a wa Sọhiihu ti Bukhaariy - 7045

Àlàyé

Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Awọn ipin àlá: 1. Àlá tí ó dáa, ohun ni àlá òtitọ ati ifunni ní iro idunu lati ọdọ Ọlọhun, eniyan lè la a funra rẹ tabi ki wọ́n la a si i. 2. Ọ̀rọ̀ tẹmi banusọ, ohun ni ọrọ ti ènìyàn ba ara rẹ sọ ní feteete (ni oju aiye) 3. Ibani nínú jẹ ati iṣẹru bani lati ọdọ èṣù (satani), ati ikoni laya jẹ lati ọdọ rẹ; lati fí kó ìbànújẹ́ bá eniyan.
  2. Kókó nkan ti wọ́n sọ nípa àlá dáada mẹta ni: Kí o dupẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ki o dunnu nipa rẹ, kí o sí sọ ọ fun àwọn eniyan, ṣugbọn awọn tí o nifẹ nikan nio laiṣe awọn ti o korira.
  3. Àpapọ̀ nkan ti wọ́n sọ nípa àlá buruku tí kò daa marun ni: ki a bere iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, ati nibi aburu èṣù, ki a sì fẹ atẹgun ẹnu wa sí apá òsì wa lẹẹmẹta nigba ti a bá jí, bẹẹ a kò gbọdọ bá ẹnikankan sọrọ nipa rẹ, ti ènìyàn náà bá fẹ sùn pada, kí ó yí ẹgbẹ ti o fi sun pada, àlá buruku naa kò nii kó ìnira ba a.
  4. Ibn Hajar sọ pe: Òye tabi idi pataki tí ó wà nibẹ ni pe tí ó bá rọ́ àlá dáada fún ẹnití kò nifẹ rẹ, irufẹ ẹni bẹẹ lè tumọ àlá náà fún-un sí nkan tí kò fẹ́, yálà nítorí pé o n binu si daada ti o rí, tabi ni ti keeta ati ẹ̀gàn, o ṣeeṣe kí àlá náà ṣẹlẹ gẹgẹ bí wọn ṣe tumọ rẹ, tabi ki ẹni ti ó lálàá máa kánjú fúnrara rẹ fún ìbànújẹ ati aidunnu ọkan, nítorí rẹ ni wọn fi paá laṣẹ pe kí ó má ṣe sọ àlá náà fún ẹniti kò nifẹ sii.
  5. Kí a máa dúpẹ́ fún Ọlọhun nigbati awọn idẹra bá n dé sinu aiye wa, ti awọn aanu sì nwá lọ́tun lọ́tun; eleyii ni òkùnfà tí idẹra náà máa fi pẹ́.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

51 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية