1. Ilé
  2. Àwọn ìsọ̀rí
  3. Adisọkan

Hadiisi Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro

عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«‌إِنَّ ‌أَثْقَلَ صَلَاةٍ عَلَى الْمُنَافِقِينَ صَلَاةُ الْعِشَاءِ وَصَلَاةُ الْفَجْرِ، وَلَوْ يَعْلَمُونَ مَا فِيهِمَا لَأَتَوْهُمَا وَلَوْ حَبْوًا، وَلَقَدْ هَمَمْتُ أَنْ آمُرَ بِالصَّلَاةِ فَتُقَامَ، ثُمَّ آمُرَ رَجُلًا فَيُصَلِّيَ بِالنَّاسِ، ثُمَّ أَنْطَلِقَ مَعِي بِرِجَالٍ مَعَهُمْ حُزَمٌ مِنْ حَطَبٍ إِلَى قَوْمٍ لَا يَشْهَدُونَ الصَّلَاةَ، فَأُحَرِّقَ عَلَيْهِمْ بُيُوتَهُمْ بِالنَّارِ».

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, sọ pe:
«Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro, ati pe mo ti wa gbero lati paṣẹ ki wọn o gbe irun duro, lẹyin naa ki n wa pa ẹnikan laṣẹ ki o ki i, lẹyin naa ki n wa gbera pẹlu awọn ọkunrin kan ti idi igi wa pẹlu wọn lọ si ọdọ awọn ijọ kan ti wọn o ki n wa ki irun ni masalaasi, ki n si sun ile wọn mọ wọn lori».

O ni alaafia Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni Sọhiihu ti Muslim - 651

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ nipa awọn munaafiki ati kikọlẹ wọn nibi wiwa ki irun, agaga julọ irun Ishai ati Asunbaa, ati pe dajudaju ti wọn ba mọ odiwọn ẹsan ati laada ti o wa nibi wiwa ki mejeeji pẹlu janmọọn ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ rirakoro gẹgẹ bi ọmọde ṣe maa n rakoro pẹlu ọwọ ati orunkun.
Ati pe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ti pinnu lati paṣẹ pe ki wọn o gbe irun duro, ki o wa fi ọkunrin kan si aaye rẹ lati ṣiwaju awọn eeyan, lẹyin naa ki o wa gbera ti awọn ti wọn gbe idi igi lọwọ si wa pẹlu rẹ, lati lọ ba awọn ọkunrin ti wọn o ki n ki irun janmọọn ninu masalaasi, lẹyin naa ki o wa da’na sun ile wọn; latari ini-agbara ẹṣẹ ti wọn ko si nibi iyẹn, - ṣugbọn ko ṣe e – latari awọn ti wọn wa ninu ile bii awọn obinrin ati awọn ọmọde ti wọn o mọ nkankan ati awọn to yatọ si wọn ninu awọn ti wọn ni idiwọ (ti wọn ni awijare), awọn ti ko si ẹṣẹ kankan fun wọn.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Aburu imaa fa sẹyin nibi kiki irun janmọọn ninu masalaasi.
  2. Awọn munaafiki o gbero pẹlu irun wọn ayaafi ṣekarini ati ṣekagbọni, nitori naa wọn ko nii wa ki irun ayaafi ni igba ti awọn eeyan maa ri wọn.
  3. Titobi ẹsan ti n bẹ nibi kiki irun Ishai ati Asunbaa pẹlu janmọọn, ati pe awọn mejeeji lẹtọọ si imaa wa ki wọn koda ko jẹ pẹlu rirakoro.
  4. Imaa ṣọ irun Ishai ati irun Asunbaa, lila lo jẹ kuro nibi jíjẹ́ munaafiki, ati pe imaa fa sẹyin nibi mejeeji ninu iroyin awọn munaafiki lo wa.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

60 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
JA 日本語 Ará Japan
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
IT Italiano Ti ede ilu Italy
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
BM Bambara البامبارية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية