عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«خَيْرُ يَوْمٍ طَلَعَتْ عَلَيْهِ الشَّمْسُ يَوْمُ الْجُمُعَةِ، فِيهِ خُلِقَ آدَمُ، وَفِيهِ أُدْخِلَ الْجَنَّةَ، وَفِيهِ أُخْرِجَ مِنْهَا، وَلَا تَقُومُ السَّاعَةُ إِلَّا فِي يَوْمِ الْجُمُعَةِ».

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀, ninu rẹ ni wọn ṣẹda Aadam, ninu rẹ ni wọn mu u wọ alujanna, ninu rẹ ni wọn mu u jade kúrò nibẹ, ọjọ́ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ".

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 854

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju eyi ti o daa julọ ninu ọjọ ti oorun ran ninu rẹ ni ọjọ Jimọ, Ninu awọn iroyin rẹ ti o fi da yatọ ni pe: Dajudaju Ọlọhun ṣẹda Aadam- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- ninu rẹ, ninu rẹ ni O mu u wọnu alujanna, ninu rẹ ni O mu u jade lati inu rẹ ti O si mu u sọkalẹ sori ilẹ̀, ọjọ igbende ko lee to afi ni ọjọ Jimọ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun ọjọ Jimọ lori awọn yoku ninu awọn ọjọ ọsẹ.
  2. Ṣisẹnilojukokoro ati jijẹ ki awọn iṣẹ oloore pọ ni ọjọ jimọ, ati igbaradi fun riri ikẹ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati titi ifiyajẹ rẹ danu.
  3. Awọn iroyin ti Jimọ fi da yatọ ti wọn dárúkọ ninu hadiiisi náà, wọn sọ pé: Ko wa fun didárúkọ ọla ti o n bẹ fun Jimọ; nitori pe imujade Aadam ati tito ọjọ igbende wọn ko ka a si ọla, wọn sọ pé: Bi ko ṣe pe gbogbo rẹ jẹ ọla ti jijade Aadam si jẹ okunfa bibẹ arọmọdọmọ ninu awọn ojiṣẹ ati awọn anabi ati awọn ẹni rere, ati pe tito ọjọ igbende jẹ okunfa yiyara gbigba ẹsan awọn ẹni rere ati titẹwọ gba nnkan ti Ọlọhun ti pese fun wọn ninu awọn apọnle.
  4. Wọn dárúkọ awọn iroyin miiran ti ọjọ Jimọ fi da yàtọ̀, yàtọ̀ si eyi ti wọn dárúkọ ninu ẹgbawa yìí, ninu rẹ ni: Ninu rẹ ni wọn gba ironupiwada Aadam, ninu rẹ ni wọn gba ẹmi rẹ, ninu rẹ ni wakati kan wa ti ẹru kan ti o jẹ olugbagbọ ko nii ṣe kongẹ rẹ ti o si n kirun ti o n beere nnkan kan lọdọ Ọlọhun afi ki O fun un ni nnkan naa.
  5. Eyi ti o lọla julọ ninu awọn ọjọ inu ọdun ni ọjọ 'Arafah, wọn sọ pé: Ọjọ́ iduran (ọdun ileya), ti eyi ti o lọla julọ ninu awọn ọjọ ọsẹ si jẹ ọjọ Jimọ, ti eyi ti o lọla julọ ninu oru si jẹ oru abiyi (lailatul qadri).

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

56 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية