عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَسِيرُ فِي طَرِيقِ مَكَّةَ، فَمَرَّ عَلَى جَبَلٍ يُقَالُ لَهُ جُمْدَانُ، فَقَالَ: «سِيرُوا هَذَا جُمْدَانُ، سَبَقَ الْمُفَرِّدُونَ» قَالُوا: وَمَا الْمُفَرِّدُونَ يَا رَسُولَ اللهِ؟ قَالَ: «الذَّاكِرُونَ اللهَ كَثِيرًا وَالذَّاكِرَاتُ».

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n rin loju ọna Makkah, ni o ba kọjá nibi oke kan ti wọn n pe e ni Jumdaan, o sọ pe: "Ẹ maa rin lọ, Jumdaan nìyí, àwọn MUFARRIDUUN ti ṣíwájú" wọn sọ pe: Awọn wo ni MUFARRIDUUN irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: Awọn ni àwọn oluranti Ọlọhun lọkunrin lọpọlọpọ ati awọn oluranti Ọlọhun lobinrin".

O ni alaafia Muslim gba a wa Sọhiihu ti Muslim - 2676

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé ipo awọn oluranti Ọlọhun lọpọlọpọ, pe wọn ti dá wà wọ́n si ti ṣáájú àwọn ti wọn yàtọ̀ si wọn pẹlu pe ọwọ wọn tẹ awọn ipo ti o ga julọ ninu alujanna onidẹra, o wa fi wọn we oke Jumdaan ti o da wa laarin awọn oke yókù.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iranti ni nnkan ti a fẹ ati kiko airoju pẹlu rẹ, dajudaju igbawaju ni ọrun maa jẹ pẹlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn itẹle, ati imọkanga nibi awọn ijọsin.
  2. Iranti Ọlọhun maa n jẹ pẹlu ahọn nikan, tabi pẹlu ọkan nìkan, tabi pẹlu ahọn ati ọkan papọ, oun ni o ga julọ ninu wọn ni ipo.
  3. Ninu awọn iranti ni àwọn àsíkìrí ti o ba sharia mu ti a dè, gẹgẹ bii awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ, ati lẹyin awọn irun ọran-anyan ati eyi ti o yàtọ̀ si wọn.
  4. An-Nawawi sọ pe: Lọ mọ pe dajudaju ọla ti o n bẹ fun iranti ko mọ lori sisọ Subhaanallah ati sisọ Laa ilaaha illallohu ati sisọ Alhamdulillah ati Allahu Akbar ati nnkan ti o jọ wọn, bi ko ṣe pe gbogbo ẹni ti o ba n ṣiṣẹ pẹlu itẹle Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ni oluranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-.
  5. Iranti Ọlọhun wa ninu eyi ti o tobi julọ ninu awọn okunfa ìdúróṣinṣin, Ọba- ti mimọ n bẹ fun Un, ti ọla Rẹ ga- sọ pe: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá pàdé ìjọ (ogun) kan, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ sì ṣe (gbólóhùn) ìrántí Allāhu ní (òǹkà) púpọ̀ nítorí kí ẹ lè jèrè) (Al-Anfal, Ayah 45)
  6. Ọ̀nà afiwe laaarin awọn oluranti Ọlọhun ati oke Jumdaan ni idawa ati ìtakété; oke Jumdaan da wa si awọn oke; gẹgẹ bẹẹ naa ni awọn oluranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- oludawa ni ẹni ti ọkan rẹ da wa ati ahọn rẹ pẹlu iranti Olúwa rẹ koda ki o wa laaarin awọn eniyan, ti n naju pẹlu awọn asiko dídáwà ti o si n ni imọlara aayun latara ọ̀pọ̀lọpọ̀ iropọ mọ awọn eniyan, ọ̀nà tí wọ́n gbà jọra tun le jẹ pe iranti jẹ okunfa ìdúróṣinṣin lori ẹsin gẹgẹ bi oke ṣe jẹ́ okunfa ìdúróṣinṣin ilẹ̀, tabi ki o jẹ igbawaju nibi awọn daadaa ni aye ati ọrun, nígbà ti ẹni ti o ba n ṣe irin ajo lati Mẹdina si Mẹka ba de Jumdaan o maa jẹ ami dide Mẹka, ẹni ti o ba ti de bẹ ti di ẹni tí ó gba iwájú, gẹgẹ bẹẹ ni oluranti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- jẹ ẹni ti o ṣáájú ẹni ti o yàtọ̀ si i latara ọ̀pọ̀lọpọ̀ iranti rẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, Ọlọhun ni O ni imọ julọ.

Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

57 Èdè
EN English Èdè Gẹ̀ẹ́sì
UR اردو Èdè Urdu
ES Español Èdè Sípéènì
ID Indonesia Èdè Indonéṣíà
UG ئۇيغۇرچە Èdè Uyghur
BN বাংলা Èdè Bangali
TR Türkçe Èdè Tọ́kì
RU Русский Èdè Rọ́ṣíà
BS Bosanski Èdè Bosnia
SI සිංහල Èdè Sinhala
HI हिन्दी Èdè India
ZH 中文 Èdè Ṣáínà
FA فارسی Èdè Páṣíà
VI Tiếng Việt Èdè Vietnamese
TL Tagalog Èdè Tagalog
KU Kurdî Ti Kurdish
HA Hausa Èdè Hausa
PT Português Ti Pọtuga
ML മലയാളം Malayalam
TE తెలుగు Èdè Telgu
SW Kiswahili Ti èdè Sawahili
TA தமிழ் Tamil
MY မြန်မာ Burmese
TH ไทย Thai
DE Deutsch Ede Jamani
PS پښتو Pashto
AS অসমীয়া Assamese
SQ Shqip Ede Alibania
SV Svenska Titi Sweden
AM አማርኛ Ìtumọ̀ sí èdè Amharic
NL Nederlands Ìtumọ̀ sí èdè Dutch
GU ગુજરાતી Titi èdè Gujarat
KY Кыргызча Ti èdè Kyrgyz
NE नेपाली Ti èdè ìlú Nepal
LT Lietuvių Ti èdè Lithuania
PRS دری Ti èdè Dari
SR Српски Ti èdè ìlú Serbia
SO Soomaali Ti èdè Somalia
TG тоҷикӣ Ti èdè ìlú Tajikistan
RW Kinyarwanda Ti èdè Rwanda
RO Română Ti èdè ìlú Romania
HU Magyar Ti èdè ilu Hungary
CS Čeština Ti èdè Czech
MOS Moore الموري
MG Malagasy Ti ede Madagascar
OM Oromoo Ti èdè ẹ̀yà Oromo
KN ಕನ್ನಡ Ti èdè Kannada
WO Wolof الولوف
AZ Azərbaycan Ti ede Azerbaijan
UZ O‘zbek Ti èdè ilu Uzbekistan
UK Українська Ti èdè ìlú Ukraine
KA ქართული الجورجية
MK Македонски المقدونية
KM ភាសាខ្មែរ الخميرية
PA ਪੰਜਾਬੀ البنجابية
MR मराठी الماراثية
KMR Kurmancî الكرمنجية